Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sefanáyà 1:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Sefanáyà ọmọ Kúsì, ọmọ Gédálíyà, ọmọ Ámáríyà, ọmọ Heṣekáyà, ní ìgbà Jósíà ọmọ Ámónì ọba Júdà.

2. “Èmi yóò mú gbogbo nǹkan kúròlórí ilẹ̀ náà pátapáta,”ni Olúwa wí.

3. “Èmi yóò mú ènìyàn àti ẹrankokúrò; èmi yóò mú àwọn ẹyẹ ojúọ̀run kúrò àti ẹja inú òkun, àtiohun ìdìgbòlù pẹ̀lú àwọnènìyàn búburú; èmi yóò ké ènìyàn kúrò lórí ilẹ̀ ayé,”ni Olúwa wí

4. “Èmi yóò na ọwọ́ mi sórí Júdààti sórí gbogbo àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Jérúsálẹ́mù.Èmi yóò sì ké kúrò níhìn-ín-yìí ìyókù àwọn Báálì, àti orúkọ àwọn abọ̀rìṣàpẹ̀lú àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà,

5. àti àwọn tí wọn ń foríbalẹ̀ tí wọnń sin ogun ọ̀run lórí òrùlé.Àwọn tí wọn ń sìn, tí wọ́n sì ń fi Olúwa búra,tí wọ́n sì ń fi Mólékì búra.

6. Àwọn tí ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ Olúwa;Àti àwọn tí kò tí wá Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì béèrè rẹ̀.

7. Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run,nítorí tí ọjọ́ Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀. Olúwa ti pèṣè ẹbọ kan sílẹ̀,ó sì ti ya àwọn alápèjẹ rẹ̀ sí mímọ́.

8. Ní ọjọ́ ẹbọ Olúwa,Èmi yóò bẹ àwọn olórí wò, àti àwọnọmọ ọba ọkùnrin,pẹ̀lú gbogboàwọn tí ó wọ àjèjì aṣọ.

9. Ní ọjọ́ náà, èmi yóò fi ìyà jẹgbogbo àwọn tí ó yẹra láti rìn lórí ìloro ẹnu ọ̀nà,tí wọ́n sì kún tẹ́ḿpìlì Olúwa wọnpẹ̀lú ìwà-ipá àti ẹ̀tàn.

10. “Ní sì ṣe ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí,“Ohùn ẹkún yóò wà láti ìhà Ibodè ẹja,híhu láti ìhà kejì wá àtiariwo ńlá láti òkè kékeré wá.

11. Hu, ẹ̀yin tí ń gbé ní agbègbè ọjà,gbogbo àwọn oníṣòwò rẹ̀ ni a ó mú kúrò,gbogbo àwọn ẹni tí ó ń ra fàdákà ni a ó sì parun.

12. Ní àkókò wọ̀n-ọn-nì, èmi yóò wá Jérúsálẹ́mù kiri pẹ̀lú fìtílà,èmi ó sì fi ìyà jẹ àwọn tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn,tí wọn sì dàbí àwọn ènìyàn tí ó sinmi sínú gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ wọn,àwọn tí wọn sì ń wí ní ọkàn wọn pé, ‘Olúwa kì yóò ṣe nǹkan kantí ó jẹ́ rere tàbí tí ó jẹ́ búburú.’

13. Nítorí náà, ọrọ̀ wọn yóò di ìkógún,àti ilé wọn yóò sì run.Àwọn yóò sì kọ́ ilé pẹ̀lú, ṣùgbọ́nwọn kì yóò gbé nínú ilé náà,wọn yóò gbin ọgbà àjàrà,ṣùgbọ́n wọn kì yóò mu ọtíWáìnì láti inú rẹ̀.

14. “Ọjọ́ ńlá Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀,ó kù sí dẹ̀dẹ̀ ó sì ń yára bọ̀kánkán. Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, ohùn ẹkúnàwọn alágbára ní ọjọ́ Olúwa yóò korò púpọ̀,

Ka pipe ipin Sefanáyà 1