Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 79:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọlọ́run àwọn orílẹ̀ èdè ti wà ilẹ̀ ìní Rẹ;wọn ti bá tẹ́ḿpìlì mímọ́ Rẹ jẹ́,wọn di Jérúsálẹ́mù kù sí òkìtì àlàpà.

2. Wọn ti fi ara òkú àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ní oúnjẹ,ẹran ara àwọn ènìyàn mímọ́ Rẹ̀ fún ẹranko ilẹ̀.

3. Wọ́n tú ẹ̀jẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí omiyí Jérúsálẹ́mù ká,kò sì sí àwọn tí yóò sìn wọ́n.

4. Àwa di ohun ẹ̀gàn sí àwọn tí o yí wa ká,àbùkù àti ìfiṣe ẹlẹ́yà sí àwọn tí ó yí wá ká.

5. Nígbà wo, Olúwa? Ní ìwọ o máa bínú títí láé?Yóò ti pẹ́ tó ti òwú Rẹ̀ yóò ha jò bi iná?

6. Tú ìbínú Rẹ̀ jáde sí orílẹ̀-èdètí kò ní ìmọ̀ Rẹ,lórí àwọn ìjọbatí kò pe orúkọ Rẹ;

7. Nítorí wọ́n ti run Jákọ́bùwọ́n sì sọ ibùgbé Rẹ̀ di ahoro

8. Má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wa sí wa lọ́rùnjẹ́ kí àánú Rẹ yà kánkán láti bá wa,nítorí ti a Rẹ̀ wá sílẹ̀ gidigidi.

9. Ràn wá lọ́wọ́, Ọlọ́run Olùgbàlà wa,fún ògo orukọ Rẹ;gbà wá kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnítorí orúkọ Rẹ.

10. Àwọn orílẹ̀ èdè yóò sì máa wí pé,“Níbo ni Ọlọ́run wọn wà?”ní ojú wa.Kí a mọ̀ láàrin àwọn orílẹ̀ èdèkí ó sì gbẹ̀san àwọn ẹ̀jẹ̀ ìránṣẹ́ Rẹ̀ tí a tú jáde.

11. Jẹ́ kí ìmí ẹ̀dùn oǹdè náà wá ṣíwájú Rẹ,gẹ́gẹ́ bí títóbi agbára Rẹìwọ ṣe ìtọ́jú àwọn ti a dá lẹ́bí ikú.

12. San án padà sí àyà àwọn aládùúgbò wa nígbà méjenípa ẹ́gàn tí wọn tí gàn ọ́ Olúwa.

13. Nígbà náà àwa ènìyàn Rẹ,àgùntàn pápá Rẹ,yóò fi ọpẹ́ fún ọ títí láé;láti ìran dé ìranni àwa ó fi ìyìn Rẹ hàn.

Ka pipe ipin Sáàmù 79