Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 52:4-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ìwọ fẹ́ràn ọ̀rọ̀ ìpanilára gbogbo,ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn!

5. Ọlọ́run yóò sì lù ọ́ bolẹ̀ láéláé,yóò sì dì ọ́ mú,yóò sì já ọ kúrò ni ibùjókòó Rẹyóò sì fà ọ́ tu kúrò lórí ilẹ̀ alààyè. Sela

6. Àwọn olódodo yóò rí, wọn yóò sì bẹ̀rùwọn yóò sì rẹ́rìn-ín Rẹ̀, wí pé,

7. Èyi ni ọkùnrin náà ti kò fi Ọlọ́run ṣe agbára Rẹ̀,bí kò ṣe ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ Rẹ̀ ni ó gbẹ́kẹ̀léó sì mu ara Rẹ̀ le nínú ìwà búburú Rẹ̀.

8. Ṣùgbọ́n èmi dàbí igi Ólífìtí ó gbilẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run;Èmi gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í kùnà láé àti láéláé.

9. Èmi yóò yìn ọ títí fún ohun tí ó ti ṣe;èmí ní ìrètí nínú orúkọ Rẹ, nítorí orúkọ Rẹ dára.Èmi yóò yìn ọ́ níwájú àwọn ènìyàn mímọ́.

Ka pipe ipin Sáàmù 52