Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 42:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Bí àgbọ̀nrín tí ń mí hẹlẹ sí ìpa odò omi,bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi n mì hẹlẹ sí ọ Ọlọ́run

2. Òùngbẹ Ọlọ́run ń gbẹ ọkàn mi, fún Ọlọ́run alààyè.Nígbà wo ni èmi ó lọ bá Ọlọ́run?

3. Oúnjẹ mi ní omijé miní ọ̀sán àti ní òru,nígbà tí àwọn ènìyàn ń wí fún mi ní gbogbo ọjọ́,“Ọlọ́run Rẹ̀ dà?”

4. Nígbà tí mo bá rántí nǹkan yìí,èmi tú ọkàn mi jáde nínú mi:èmi ti bá ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn lọ,èmi bá wọn lọ sí ilé Ọlọ́runpẹ̀lú ohùn ayọ̀ àti ìyìn,pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń pa ọjọ́ mímọ́ mọ́.

5. Èéṣe tí o fi n rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mi?Èéṣe tí ara Rẹ kò fi lélẹ̀ nínú mi?Ìwọ ṣe ìrètí ni ti Ọlọ́run,nítorí èmi yóò sáà máa yìn ín.

6. Olùgbàlà mi àtiỌlọ́run mi,ọkàn mi ń rẹ̀wẹ̀sì nínú mi:nítorí náà, èmi ó rántí Rẹláti ilẹ̀ Jọ́dánì wá,láti Hámónì láti òkè Mísárì.

7. Ibú omi ń pe ibú ominípa híhó omi ṣíṣàn Rẹ̀gbogbo rírú omi àti bíbì omi Rẹ̀bò mí mọ́lẹ̀.

8. Ní ọ̀sán ní Olúwa ran ìfẹ́ Rẹ̀,àti ni àṣálẹ́ ni orin Rẹ̀ wà pẹ̀lú miàdúrà sí Ọlọ́run ayé mi.

9. Èmi wí fún Ọlọ́run àpátà mi,“Èéṣe tí ìwọ fi gbàgbé mi?Èéṣe tí èmi o fi máa rìn nínú ìbànújẹ́,nítorí ìnilára ọ̀ta?”

10. Bí ẹni pé idà egungun mi ni ẹ̀gàn tíàwọn ọ̀ta mi ń gàn mí,Bí wọn ti ń béèrè ni gbogbo ọjọ́.“Níbo ni Ọlọ́run Rẹ wà?”

Ka pipe ipin Sáàmù 42