Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 12:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ràn wá lọ́wọ́, Olúwa nítorí ẹni ìwà bí Ọlọ́run kò sí mọ́;Olótìítọ́ tí pòórá kúrò láàrin àwọn ènìyàn.

2. Olúkúlùkù ń parọ́ fún aládùúgbò rẹ̀;ètè èké wọn ń sọ ẹ̀tàn.

3. Kí Olúwa kí ó gé ètè èké wọnàti gbogbo ahọ́n ìfọ́nnu

4. tí ó wí pé, “Àwa ó borí pẹ̀lú ahọ́n wa;àwa ní ètè wa: ta ni ọ̀gá wa?”

5. “Nítorí ìnilára àwọn aláìlágbáraàti ìkéróra àwọn aláìní,Èmi yóò dìde nísinsin yìí” ni Olúwa wí.“Èmi yóò dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn tí ń ṣe àrankàn wọn”

6. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì jẹ aláìlábùkù,gẹ́gẹ́ bí fàdákà ti a yọ́ nínú ìléru àmọ́,tí a sọ di mímọ́ nígbà méje.

7. Olúwa, ìwọ yóò pa wá mọ́kí o sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí títí láé.

Ka pipe ipin Sáàmù 12