Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Rúùtù 2:8-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Nígbà náà ni Bóásì sọ fún Rúùtù pé, “Gbọ́ ọmọbìnrin mi, má ṣe lọ sí oko mìíràn láti ṣa ọkà, má sì ṣe kúrò ní ibi. Dúró níbí pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́-bìnrin mi.

9. Wo ibi tí wọ́n ti ń kórè kí o sì máa tẹ̀lé àwọn obìnrin. Mo ti pàṣẹ fún àwọn ọkùnrin kí wọ́n má ṣe fi ọwọ́ kàn ọ́. Nígbàkugbà tí òǹgbẹ bá sì ń gbẹ ọ́, lọ kí ó sì mu omi nínú àmù èyí tí àwọn ọkùnrin ti pọn omi sí nínú.”

10. Rúùtù wólẹ̀, ó sì wí fún Bóásì pé, “Èéṣe tí èmi fi bá ojúrere rẹ pàdé tó báyìí, tí o sì kíyèsí mi, èmi àjèjì àti àlejò?”

11. Bóásì sì fèsì wí pé, “Èmi ti gbọ́ gbogbo bí o ti ń ṣe sí ìyá ọkọ ọ̀ rẹ láti ìgbà tí ọkọ rẹ ti kú àti bí o ti ṣe fi baba àti ìyá rẹ àti ilẹ̀ rẹ sílẹ̀, tí o sì wá láti gbé láàárin àwọn ènìyàn tí ìwọ kò mọ̀ rí tẹ́lẹ̀.

12. Kí Olúwa kí ó san ẹ̀san ohun tí o ṣe fún ọ. Kí o sì gba èrè kíkún láti ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì abẹ́ ìyẹ́ ẹni tí ìwọ sá wá fún ààbò.”

13. Rúùtù sì fèsì wí pé, “Kí èmi kí ó máa rí ojúrere láti ọ̀dọ̀ rẹ ṣíwájú sí i olúwa mi. Ìwọ ti tù mí nínú nípa sísọ ọ̀rọ̀ rere sí ìránṣẹ́-bìnrin rẹ, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé èmi kò tó ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́-bìnrin rẹ.”

14. Nígbà tí àkókò oúnjẹ sì tó, Bóásì sọ fún Rúùtù pé, “Wá gba ìwọ̀n àkàrà yí kí o sì fi run wáìnì kíkan.”Ó sì jókòó pẹ̀lú àwọn olùkórè, Bóásì sì fún-un ní ọkà yíyan. Ó sì jẹ́, ó yó, ó sì tún ṣẹ́kù.

15. Nígbà tí ó sì dìde láti máa ṣa ọkà, Bóásì pàṣẹ fún àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ wí pé, “Bí ó tilẹ̀ ń ṣà láàárin oko ọkà pàápàá, ẹ má ṣe dí i lọ́wọ́.

Ka pipe ipin Rúùtù 2