Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Rúùtù 1:2-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Orúkọ ọkùnrin náà ń jẹ́ Elimélékì, orúkọ ìyàwó rẹ̀ ni Náómì, orúkọ àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì sì ni Málónì àti Kílíónì àwọn ará Éfúrétà, ti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Júdà. Wọ́n sì lọ sí ilẹ̀ Móábù, wọ́n ń gbé níbẹ̀.

3. Ní àsìkò tí wọ́n ń gbé ibẹ̀, Elimélékì, ọkọ Náómì kú, ó sì ku òun (Náómì) pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjèèjì.

4. Wọ́n sì fẹ́ àwọn ọmọbìnrin ará Móábù méjì, orúkọ, ọ̀kan ń jẹ́ Órípà, èkejì sì ń jẹ́ Rúùtù. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n sì ti gbé níbẹ̀ fún bí ọdún mẹ́wàá,

5. Málónì àti Kílíónì náà sì kú, Náómì sì wà láìsí ọkọ tàbí ọmọ kankan fún-un mọ́.

6. Nígbà tí Náómì gbọ́ ní Móábù tí ó wà wí pé Olúwa ti bẹ àwọn ènìyàn rẹ̀ wò nípa fí fún wọn ní ọ̀pọ̀ oúnjẹ. Ó sì dìde pẹ̀lú àwọn ìyàwó ọmọ rẹ̀ méjèèjì láti padà sí ìlú rẹ̀.

7. Òun pẹ̀lú àwọn ìyàwó ọmọ rẹ̀ méjèèjì ni wọ́n jọ fi ibi tí ó ń gbé sílẹ̀ tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò wọn padà sí ilẹ̀ Júdà.

8. Ṣùgbọ́n ní ojú ọ̀nà, Náómì wí fún àwọn aya ọmọ rẹ̀ méjèèjì pé, “Kí ẹnikọ̀ọ̀kan yín padà sí ilé ìyá rẹ̀. Kí Olúwa ṣe àánú fún yín bí ẹ ti ṣe sí èmi àti àwọn ọkọ yín tí ó kú.

9. Kí Olúwa kí ó fi yín lọ́kàn balẹ̀ ní ilé ọkọ mìíràn.”Náómì sì fi ẹnu kò wọ́n ní ẹnu wí pé “Ó dìgbà,” Wọ́n sì sunkún kíkan kíkan.

10. Wọ́n sì wí fún-un pé, “Rárá, a ó bà ọ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ.”

11. Ṣùgbọ́n Náómì dáhùn wí pé, “Ẹ padà sílé ẹ̀yin ọmọ mi. Nítorí kí ni ẹ fi fẹ́ wá pẹ̀lú mi? Ṣé mo tún le bí àwọn ọmọkùnrin mìíràn ni, tí ó le se ọkọ yin?

Ka pipe ipin Rúùtù 1