Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 29:9-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn bá lọ sí ilé ẹjọ́ pẹ̀lú aláìgbọ́naláìgbọ́n a máa bínú a sì máa jà, kò sì ní sí àlàáfíà.

10. Àwọn tí ó ń tàjẹ̀ sílẹ̀ kòrí ẹni-dídúró-ṣinṣinwọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa olódodo.

11. Aláìgbọ́n ènìyàn fi gbogbo ẹ̀nú rẹ̀ bínúṣùgbọ́n ọlọgbọ́n ènìyàn a máa kó ìbínú rẹ̀ ní ìjánu.

12. Bí olórí bá fetí sí irọ́,gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ a di ènìyàn búburú lójú rẹ̀.

13. Tálákà ènìyàn àti aninilára jọ ní àbùdá yìí, Olúwa jẹ́ kí ojú àwọn méjèèjì máa ríran.

14. Bí ọba kan bá ń ṣe ìdájọ́ talákà pẹ̀lú òtítọ́ìtẹ́ ìjọba rẹ yóò fìdí múlẹ̀ nígbà gbogbo.

15. Ọ̀pá ìbániwí ń fún ni ní ọgbọ́nṣùgbọ́n ọmọ tí a fi sílẹ̀ fúnra rẹ̀ a dójú ti ìyá rẹ̀.

16. Nígbà tí ènìyàn búburú ń gbilẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀ṣẹ̀ ń gbilẹ̀ṣùgbọ́n Olódodo yóò rí ìṣubú wọn.

17. Bá ọmọ rẹ wí, yóò sì fún ọ ní àlàáfíàyóò sì mú inú dídùn wá sí inú ọkàn rẹ.

18. Níbi tí kò ti sí ìfihàn, àwọn ènìyàn a gbé ìgbé ayé àìbìkítà.Ṣùgbọ́n ìbùkún ní fún àwọn tí ń pa òfín mọ́.

19. A kò le fi ọ̀rọ̀ lásán kìlọ̀ fún ìránṣẹ́bí ó tilẹ̀ yé e, kò ní kọbi-ara-síi.

20. Njẹ́ ó rí ènìyàn tí ń kánjú sọ̀rọ̀?Ìrètí wà fún aláìgbọ́n jù ú lọ.

21. Bí ènìyàn kan bá kẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ lákẹ̀ẹ́jù láti kékeréyóò mú ìbànújẹ́ wá ní ìgbẹ̀yìn.

22. Oníbìínú ènìyàn a ru ìjà sókè,Onínú-fùfù ènìyàn a sì máa dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀.

23. Ìgbéraga ènìyàn a máa sọ ọ́ di ẹni ilẹ̀ṣùgbọ́n onírẹ̀lẹ̀ ènìyàn a máa gba iyì kún iyì.

24. Ẹni tí ó ń ran olè lọ́wọ́ gan an ni ọ̀ta rẹ̀O ń gbọ́ epe olóhun kò sì le è fọhùn.

Ka pipe ipin Òwe 29