Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 27:23-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Rí i dájú pé o mọ ipò tí àwọn agbo àgùntàn rẹ wàbojú tó àwọn agbo màlúù rẹ dáradára;

24. nítorí ọrọ̀ kì í pẹ́ lọ títíadé kì í sì í wà lórí títí láéláé.

25. Nígbà tí a bá kó koríko jọ láti orí òkè

26. àwọn àgùntàn yóò pèṣè aṣọ fún ọ,àti ewúrẹ́ yóò pèṣè owó oko.

27. Ìwọ yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ mílíkì ewúrẹ́láti bọ́ ọ àti ìdílé rẹàti láti tọ́jú àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ.

Ka pipe ipin Òwe 27