Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 24:9-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ète òmùgọ̀ ènìyàn jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,àwọn ènìyàn sì kórìíra ẹlẹ́gàn.

10. Bí ìwọ bá dákú lásìkò ìdààmúbáwo ni agbára rẹ ha ti kéré tó!

11. Gba àwọn tí a ń wọ́ lọ síbi ikú là;fa àwọn tó ń ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n lọ síbi ìparun padà.

12. Bí ìwọ bá wí pé, “Ṣùgbọ́n a kò mọ nǹkankan nípa èyí,”ǹjẹ́ ẹni tí ń díwọ̀n ọkàn kò kíyèsíi? Ǹjẹ́ ẹni tí ń ṣọ́ ẹ̀mí rẹ kò mọ̀ ọ́?Ǹjẹ́ kò ní san án fún ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó ti ṣe?

13. Jẹ oyin, ìwọ ọmọ mi, nítorí tí ó dára,oyin láti inú afárá oyin dùn lẹ́nu.

14. Mọ̀ pẹ̀lú pé ọgbọ́n pẹ̀lú dùn fún ọkàn rẹbí ìwọ bá rí i ìrètí ọjọ́ iwájú wà fún ọìrètí rẹ kì yóò sì já sófo.

15. Má ṣe ba ní ibùba bí i arúfin dé ilé Olódodo,má ṣe kó ibùgbé è rẹ̀ lọ;

16. Nítorí bí olódodo ènìyàn bá tilẹ̀ ṣubú ní ìgbàméje, yóò tún padà dìde ṣáá ni,ṣùgbọ́n ìdàámú yóò fa ènìyàn búburú lulẹ̀.

17. Má ṣe yọ̀ nígbà tí ọ̀tá rẹ bá ṣubú;nígbà tí ó bá kọsẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yọ̀

18. àìṣe bẹ́ẹ̀ Olúwa yóò rí i yóò sì bínúyóò sì yí ìbínú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.

19. Má ṣe fòyà nítorí àwọn ènìyàn ibitàbí jowú àwọn ènìyàn búburú,

Ka pipe ipin Òwe 24