26. Ìdáhùn òtítọ́ó dàbí ìfẹnu-koni-ní-ẹnu.
27. Parí gbogbo iṣẹ́ ajé rẹsì rí i pé oko rẹ ti ṣe dáradára;lẹ́yìn náà kọ́ ilé rẹ.
28. Má ṣe rojọ́ èké mọ́ aládúgbò rẹ láìnídìí,tàbí kí o fi ètè rẹ tannijẹ.
29. Má ṣe wí pé, “Mà á ṣe é fún un gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fún mi;Èmi yóò san ohun tí ó ṣe fún mi padà fún un.”
30. Mo kọjá níbi oko ọ̀lẹ,mo kọjá níbi oko aláìgbọ́n ènìyàn;
31. ẹ̀gún ti hù ní ibi gbogbo,koríko ti gba gbogbo oko náà
32. Mo fi ọkàn mi sí nǹkan tí mo kíyèsímo sì kẹ́kọ̀ọ́ lára ohun tí mo rí;
33. oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀,ìkáwọ́ gbera díẹ̀ láti sinmi
34. Òsì yóò sì dé bá ọ bí adigunjalèàti àìní bí olè.