Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 18:17-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Ẹni tí ó kọ́kọ́ rojọ́ máa ń dàbí i pé ó jàretítí ẹlòmíràn yóò fi bọ́ síwájú kí ó sì tú àsírí gbogbo.

18. Ìbò dídì máa ń parí ìjàa sì mú kí àwọn alátakò méjì jìnnà sí ara wọn.

19. Arákùnrin tí a ṣẹ̀ ṣòroó yípadà ju ìlú olódi lọ,ìjà sì dàbí ibodè ìlú olódi ńlá tí a ṣe.

20. Láti inú èso ẹnu rẹ̀ ikùn ènìyàn a yó;láti inú ìkórè ẹnu rẹ̀ ni ó ti jẹ yó.

21. Ahọ́n ni agbára ìyè àti ikú,àwọn tí ó sì fẹ́ràn rẹ̀ yóò jẹẹ́.

22. Ẹni tí ó rí aya fẹ́, rí ohun rere,Ó sì gba ojú rere lọ́dọ̀ Olúwa.

23. Tálákà ń bẹ̀bẹ̀ fún àánú,Ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ a dáhùn pẹ̀lú ìkanra.

24. Ènìyàn tí ó ní ọ̀rẹ́ púpọ̀ le è parunṢùgbọ́n ọ̀rẹ́ kan wà tí ó sún mọ́ ni tímọ́ tímọ́ ju arákùnrin.

Ka pipe ipin Òwe 18