1. Níbo ni olùfẹ́ rẹ lọ,Ìwọ arẹwà jùlọ láàárin àwọn obìnrin?Níbo ni olùfẹ́ rẹ yà sí,kí a lè bá ọ wá a?
2. Olùfẹ́ mi ti ṣọ̀kalẹ̀ lọ sínú ọgbà rẹ̀,sí ibi ibùsùn tùràrí,láti máa jẹ nínú ọgbàláti kó ìtànná lílì jọ.
3. Èmi ni ti olùfẹ́ mi, olùfẹ́ mi sì ni tèmi,Ó ń jẹ láàárin ìtànná lílì,
4. Ìwọ lẹ́wà olùfẹ́ mi, bí i Tírísà,Ìwọ lẹ́wà bí i Jérúsálẹ́mù,ìwọ lẹ́rù bí ogun pẹ̀lú ọ̀págun.
5. Yí ojú rẹ kúrò lára mi;nítorí ojú rẹ borí mi.Irun rẹ rí bí i ọ̀wọ́ ewúrẹ́tí ó sọ̀kalẹ̀ wá láti Gílíádì.
6. Eyín rẹ rí bí ọ̀wọ́ àgùntàn,Tí ó gòkè láti ibi ìwẹ̀ rẹ̀ wá,gbogbo wọn bí ìbejì,kò sì sí ọ̀kankan tí ó yàgàn nínú wọn.
7. Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ lẹ́bá ìbòjú rẹ,rí bí ẹ̀là èso pómégíránéètì.
8. Ọgọ́ta ayaba ní ń bẹ níbẹ̀,àti ọgọ́rin àlè,àti àwọn wúndíá láìníye.
9. Àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi, ọ̀kan ni,ọ̀kan ṣoṣo ọmọbìnrin ìyá rẹ,ààyò ẹyọkan ṣoṣo ẹni tí ó bí i.Àwọn obìnrin rí i wọ́n pè é ní alábùkún fúnÀwọn ayaba àti àwọn àlè gbé oríyìn fun-un
10. Ta ni èyí tí ó tàn jáde bí i ìràwọ̀ òwúrọ̀,tí ó dára bí òṣùpá, tí ó mọ́lẹ̀ bí òòrùn,tí ó ní ẹ̀rù bí i jagunjagun pẹ̀lú ọ̀págun?