Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Sólómónì 3:8-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Gbogbo wọn ni ó mú idà lọ́wọ́,gbogbo wọn ní ìmọ̀ nínú ogun,Idà oníkálùkù wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀,Wọ́n múra sílẹ̀ fún ìdágìrì òru

9. Sólómónì ọba ṣe àkéte fún ara rẹ̀;Ó fi igi Lébánónì ṣe é.

10. Ó fi fàdákà ṣe òpó rẹ̀Ó fi wúrà ṣe ibi ẹ̀yìn rẹ̀Ó fi elésè àlùkò ṣe ibùjókòó rẹ̀,Inú rẹ̀ ni ó kọ àwọn ọ̀rọ̀ ìfẹ́ wọ̀nyí sí“Pẹ̀lú ìfẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù.”

11. Ẹ jáde wá, ẹyin ọmọbìnrin Ṣíónì,kí ẹ sì wo ọba Sólómónì tí ó dé adé,Adé tí ìyá rẹ̀ fi dé eNí ọjọ́ ìgbéyàwó rẹ̀,Ní ọjọ́ ayọ̀ ọkàn rẹ̀.

Ka pipe ipin Orin Sólómónì 3