Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Oníwàásù 9:4-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ẹnikẹ́ni tí ó wà láàrin alààyè ní ìrètí—kódà ààyè ajá ṣàn dáadáa ju òkú ẹkùn lọ!

5. Nítorí pé ẹni tí ó wà láàyè mọ̀ wí pé àwọn yóò kúṣùgbọ́n òkú kò mọ ohun kanwọn kò ní èrè kankan mọ́,àti pé kódà ìrántí wọn tí di ohun ìgbàgbé.

6. Ìfẹ́ wọn, ìríra wọnàti ìlara wọn ti parẹ́:láéláé kọ́ ni wọn yóò tún ní ìpínnínú ohunkóhun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn.

7. Lọ jẹ oúnjẹ rẹ pẹ̀lú ayọ̀, kí o sì mu ọtí wáìnì rẹ pẹ̀lú inú-dídùn dé ọkàn, nítorí pé ìṣinyìí ni Ọlọ́run síjú àánú wo ohun tí o ṣe.

8. Má a wọ aṣọ funfun nígbàkugbà kí o sì máa fi òróró yan oríìrẹ nígbà gbogbo.

9. Má a jẹ ayé pẹ̀lú ìyàwó rẹ, ẹni tí o fẹ́ràn, ní gbogbo ọjọ́ ayé àìní ìtumọ̀ yí tí Ọlọ́run ti fi fún ọ lábẹ́ oòrùn—gbogbo ọjọ́ àìní ìtumọ̀ rẹ. Nítorí èyí ni ìpín tìrẹ ní ayé àti nínú iṣẹ́ wàhálà rẹ ní abẹ́ oòrun.

Ka pipe ipin Oníwàásù 9