Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Oníwàásù 9:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà ni mo wá ronú lórí gbogbo èyí, tí mo sì parí rẹ̀ pé, olòtìítọ́ àti ọlọ́gbọ́n àti ohun tí wọ́n ń ṣe wà ní ọwọ́ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kò sí ènìyàn tí ó mọ̀ bó yá ìfẹ́ tàbí ìríra ni ó ń dúró de òun.

2. Àyànmọ́ kan náà ni gbogbo wọn ń pín—olótìítọ́ àti òsìkà, rere àti ibi, mímọ́ àti àìmọ́, àwọn tí ó ń rúbọ àti àwọn tí kò rúbọ.Bí ó ti wà pẹ̀lú ọkùnrin rerebẹ́ẹ̀ náà ni ó wà pẹ̀lú ẹlẹ́ṣẹ̀bí ó ti wà pẹ̀lú àwọn tí ó ń ṣe ìbúrabẹ́ẹ̀ náà ni ó wà pẹ̀lú àwọn tí ó ń bẹ̀rù láti ṣe ìbúra.

3. Ohun búburú ni èyí jẹ́ nínú gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn. Ìpín kan ṣoṣo ni ó ń dúró de gbogbo wọn, ọkàn ènìyàn pẹ̀lú kún fún ibi, ìṣínwín sì wà ní ọkàn wọn nígbà tí wọ́n wà láàyè àti nígbà tí wọ́n bá darapọ̀ mọ́ òkú.

4. Ẹnikẹ́ni tí ó wà láàrin alààyè ní ìrètí—kódà ààyè ajá ṣàn dáadáa ju òkú ẹkùn lọ!

5. Nítorí pé ẹni tí ó wà láàyè mọ̀ wí pé àwọn yóò kúṣùgbọ́n òkú kò mọ ohun kanwọn kò ní èrè kankan mọ́,àti pé kódà ìrántí wọn tí di ohun ìgbàgbé.

6. Ìfẹ́ wọn, ìríra wọnàti ìlara wọn ti parẹ́:láéláé kọ́ ni wọn yóò tún ní ìpínnínú ohunkóhun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn.

7. Lọ jẹ oúnjẹ rẹ pẹ̀lú ayọ̀, kí o sì mu ọtí wáìnì rẹ pẹ̀lú inú-dídùn dé ọkàn, nítorí pé ìṣinyìí ni Ọlọ́run síjú àánú wo ohun tí o ṣe.

Ka pipe ipin Oníwàásù 9