Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Oníwàásù 2:2-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. “Mo wí fún ẹ̀rín pé òmùgọ̀ ni. Àti fún ire-ayọ̀ pé kí ni ó ń ṣe?”

3. Mo tiraka láti dun ara mi nínú pẹ̀lú ọtí wáìnì, àti láti fi ọwọ́ lé òmùgọ̀,—ọkàn mi sì ń tọ́ mi pẹ̀lú ọgbọ́n. Mo fẹ́ wo ohun tí ó yẹ ní ṣíṣe fún ènìyàn ní abẹ́ ọ̀run ní ìwọ̀nba ọjọ́ ayé rẹ̀.

4. Mo ṣe àwọn iṣẹ́ ńlá ńlá: Mo kọ́ ilé púpọ̀ fún ara mi, mo sì gbin ọgbà àjàrà púpọ̀.

5. Mo ṣe ọgbà àti àgbàlá, mo sì gbin onírúurú igi eléso sí inú wọn.

6. Mo gbé adágún láti máa bu omi rin àwọn igi tí ó ń hù jáde nínú ọgbà.

7. Mo ra àwọn ẹrú ọkùnrin àti àwọn ẹrú obìnrin, mo sì tún ní àwọn ẹrú mìíràn tí a bí sí ilé mi. Mo sì tún ní agbo àgùntàn ju ẹnikẹ́ni ní Jérúsálẹ́mù lọ.

8. Mo kó wúrà àti wúrà jọ fún ara mi àti àwọn ohun ìṣúra ti ọba àti ìgbéríko. Mo ní àwọn akọrin ọkùnrin àti obìnrin. Mo sì ní onírúurú àwọn obìnrin tí ọkan ọkùnrin le e fà sí.

9. Mo di ẹni ńlá ju ẹnikẹ́ni tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù ṣáájú mi. Nínú gbogbo èyí, ọgbọ́n mi kò fi mí sílẹ̀.

10. Èmi kò jẹ́ kí ojú mi ṣe aláìrí ohun tí ó bá ń fẹ́.N kò sì jẹ́ kí ọkàn mi ó ṣe aláìní ìgbádùn.Ọkàn mi yọ̀ nínú gbogbo iṣẹ́ mi,èyí sì ni èrè fún gbogbo wàhálà mi.

11. Ṣíbẹ̀, nígbà tí mo wo gbogbo ohun tí ọwọ́ mi ti ṣeàti ohun tí mo ti ṣe wàhálà láti ní:gbogbo rẹ̀, aṣán ni. Ó dàbí ẹnigbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́, kò sí èrè kan ní abẹ́ oòrùn;ọgbọ́n àti òmùgọ̀, aṣán ni.

12. Nígbà náà ni mo tún bẹ̀rẹ̀ sí ọgbọ́n,àti ìsínwín àti àìgbọ́nkí ni ọba tí ó jẹ lẹ́yìn tí ọba kan kú le è ṣeju èyí tí ọba ìṣáájú ti ṣe lọ.

13. Mo sì ri wí pé ọgbọ́n dára ju òmùgọ̀gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ ti dára ju òkùnkùn lọ.

14. Ojú ọlọ́gbọ́n ń bẹ lágbárí rẹ̀,nígbà tí aṣiwèrè ń rìn nínú òkùnkùn,ṣùgbọ́n mo wá padà mọ̀wí pé ìpín kan náà ni ó n dúró de ìsọ̀rí àwọn ènìyàn méjèèjì.

15. Nígbà náà ni mo rò nínú ọkàn wí pé“Irú ìpín tí òmùgọ̀ ní yóò bá èmi náà pẹ̀lúkí wá ni ohun tí mo jẹ ní èrè nípa ọgbọ́n”?Mo ṣọ nínú ọkàn mi wí pé,“Aṣán ni eléyìí pẹ̀lú.”

16. Nítorí pé ọlọgbọ́n ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí i òmùgọ̀, a kì yóò rántí rẹ̀ fún ìgbà pípẹ́;gbogbo wọn ni yóò di ohun ìgbàgbé ní ọjọ́ tó ń bọ̀ikú tí ó pa aṣiwèrè náà ni yóò pa ọlọgbọ́n ènìyàn.

17. Nítorí náà, mo kórìíra ìwà-láàyè, nítorí pé iṣẹ́ tí wọn ń ṣe ní abẹ́ oòrùn ti mú ìdààmú bá mi. Gbogbo rẹ̀ aṣán ni, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni.

18. Mo kóòríra gbogbo ohun tí mo ti ṣíṣẹ́ fún ní abẹ́ oòrùn, nítorí pé mo ní láti fi wọ́n sílẹ̀ fún ẹni tí ó wà lẹ́yìn mi ni.

19. Ta ni ó wá mọ̀ bóyá ọlọgbọ́n ènìyàn ni yóò jẹ́ tàbí òmùgọ̀? Ṣíbẹ̀ yóò ní láti ṣe àkóso lórí gbogbo iṣẹ́ tí mo tí ṣe yìí pẹ̀lú.

Ka pipe ipin Oníwàásù 2