Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Oníwàásù 12:10-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Oníwàásù wádìí láti rí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó tọ̀nà, ohun tí ó kọ sì dúró ṣinṣin ó sì jẹ́ òtítọ́.

11. Ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n dàbí ẹ̀gún, àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ wọn sì dàbí èso tí a kàn pọ̀ dáradára tí olùṣọ́-àgùntàn kan fi fún ni.

12. Àti síwájú láti inú èyí, Ọmọ-ọ̀n mi, gba ìmọ̀ràn.Nínú ìwé púpọ̀, òpin kò sí, ìwé kíkà púpọ̀ a máa mú ara ṣàárẹ̀.

13. Níṣinsìn yìí,òpin gbogbo ọ̀rọ̀ tí a gbọ́ ni pé:Bẹ̀rù Ọlọ́run, kí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́,nítorí èyí ni ojúṣe gbogbo ènìyàn.

14. Nítorí Ọlọ́run yóò ṣe ìdájọ́ olúkúlùkù iṣẹ́àti ohun ìkọ̀kọ̀,kì bá à ṣe rere kì bá à ṣe búburú.

Ka pipe ipin Oníwàásù 12