Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 9:4-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Wọ́n fún un ní àádọ́rin ṣékélì fàdákà láti ilé òrìṣà Bááli-Béritì, Ábímélékì fi owó náà gba àwọn jàǹdùkú àti aláìníláárí ènìyàn tí wọ́n sì di olùtẹ̀lé rẹ̀.

5. Ó kó wọn lọ sí ilé baba rẹ̀ ní Ófírà, níbẹ̀ ní orí òkúta kan ṣoṣo ni ó ti pa àádọ́rin nínú àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn Jérú-Báálì, ṣùgbọ́n Jótamù, àbíkẹ́yìn nínú àwọn ọmọ Jérúb-Báálì, bọ́ yọ nítorí pé ó sá pamọ́.

6. Gbogbo àwọn ará Ṣékémù àti àwọn ará Bẹti-Mílò pàdé pọ̀ ní ẹ̀bá igi óákù ní ibi òpó ní Ṣékémù láti fi Ábímélékì jọba.

7. Nígbà tí wọ́n sọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ yìí fún Jótamù, ó gun orí ṣóńṣó òkè Gérísímì lọ, ó sì ké lóhùn rara pé, “Ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin àgbààgbà Ṣékémù, kí Olúwa le tẹ́tí sí yín.

8. Ní ọjọ́ kan àwọn igi jáde lọ láti yan ọba fún ara wọn. Wọ́n pe igi Ólífì pé, ‘Wá ṣe ọba wa.’ ”

9. “Ṣùgbọ́n igi Ólífì dá wọn lóhùn pé, ‘Èmi yóò ha fi òróró mi sílẹ̀ èyí tí a ń lò láti fi ọ̀wọ̀ fún àwọn ọlọ́run àti ènìyàn kí èmi sì wá ṣolórí àwọn igi?’

10. “Àwọn igi sọ fún igi ọ̀pọ̀tọ́ pé, ‘Wá jọba ní orí wa.’

11. “Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀tọ́ dá wọn lóhùn pé, ‘Kí èmi fi èṣo mi tí ó dára tí ó sì dùn sílẹ̀ láti wá ṣolórí àwọn igi?’

12. “Àwọn igi sì tún sọ fún àjàrà pé, ‘Wá, kí o ṣe ọba wa.’

13. “Ṣùgbọ́n àjàrà dáhùn pé, ‘Ṣé kí èmi dẹ́kun àti máa so èṣo wáìnì mi èyí tí ó ń mú inú Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn dùn láti máa ṣe olórí àwọn igi?’

Ka pipe ipin Onídájọ́ 9