Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 9:15-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. “Igi ẹ̀gún dá àwọn igi lóhùn pé, ‘Bí lótítọ́ ni ẹ bá fẹ́ yàn mí ní ọba yín. Ẹ sá àṣálà sí abẹ́ ìbòji mi; ṣùgbọ́n tí kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí ìná jáde láti inú igi ẹ̀gún kí ó sì jó àwọn igi Kédárì àti ti Lẹ́bánónì run!’

16. “Báyìí tí ó bá jẹ́ pé ẹ̀yín ṣe ohun tí ó ní ọlá àti pẹ̀lú ẹ̀mí òtítọ́ ní fífi Ábímélékì jọba, tí ó bá ṣe pé ohun tí ó tọ́ ni ẹ ṣe sí Jérú-Báálì àti ìdílé rẹ̀, bí ẹ bá san ẹ̀san tó yẹ fún un.

17. Nítorí pé baba mi jà nítorí yín, ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu láti gbà yín sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Mídíánì;

18. ṣùgbọ́n lónìí ẹ̀yin ṣọ̀tẹ̀ sí ilé baba mi, ní orí òkúta kan ṣoṣo ni ẹ ti pa àwọn àádọ́rin ọmọ rẹ̀, ẹ̀yin sì ti fi Ábímélékì ọmọ ẹrú-bìnrin rẹ̀ jọba lórí àwọn ènìyàn Ṣékémù nítorí tí ó jẹ́ arákùnrin yín.

19. Bí ohun tí ẹ ṣe sí Jérú-Báálì àti ìdílé rẹ̀ bá jẹ́ ohun tí ó yẹ, tí ẹ sì ṣe òtítọ́ inú sí i, kí ẹ ní ayọ̀ nínú Ábímélékì kí òun náà sì ní ayọ̀ nínú yín.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 9