Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 8:22-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Àwọn ará Ísírẹ́lì wí fún Gídíónì pé, “Jọba lórí wa—ìwọ, àwọn ọmọ rẹ àti àwọn ọmọ-ọmọ rẹ pẹ̀lú, nítorí tí ìwọ ti gbà wá lọ́wọ́ àwọn ará Mídíánì.”

23. Ṣùgbọ́n Gídíónì dá wọn lóhùn pé, “Èmi kì yóò jọba lórí yín, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ mi kì yóò jọba lórí yín. Olúwa ni yóò jọba lórí yín.”

24. Ó sì wí pé, “Mo ní ẹ̀bẹ̀ kan tí mo fẹ́ bẹ̀ yín kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín fún mi ní yẹtí kọ̀ọ̀kan láti inú ohun ti ọkàn yín láti inú ìkógun.” (Àṣà àwọn ará Ísímáílì ni láti máa fi yẹtí wúrà sétí.)

25. Wọ́n dáhùn pé, “Tayọ̀-tayọ̀ ni àwa yóò fi wọ́n sílẹ̀.” Wọ́n tẹ́ aṣọ kan sílẹ̀ ọkùnrin kọ̀ọ̀kan sì ń sọ yẹtí kọ̀ọ̀kan tí ó kàn wọ́n láti ibi ìkógun ṣíbẹ̀.

26. Ìwọ̀n òrùka wúrà tí ó bèèrè fún tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán, ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn ún méje (1700) ìwọ̀n ṣékélì èyí tó kìlógírámù mọ́kàndínlógún ààbọ̀ (19.5 kilogram), láìka àwọn ohun ọ̀ṣọ́ àti ohun sísorọ̀ tí ó wà lára ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn àti aṣọ eléṣé àlùkò tí àwọn ọba Mídíánì ń wọ̀ tàbí àwọn ìlẹ̀kẹ̀ tí ó wà ní ọrùn àwọn ràkúnmí wọn.

27. Gídíónì fi àwọn wúrà náà ṣe Éfódì èyí tí ó gbé kalẹ̀ ní Òfírà ìlú rẹ̀. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì sọ ara wọn di aṣẹ́wó nípa sínsìn ní ibẹ̀. Ó sì di ẹ̀ṣẹ̀ fún Gídíónì àti ìdílé rẹ̀.

28. Báyìí ni a ṣe tẹrí àwọn ará Mídíánì ba níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tún gbérí mọ́. Ní ọjọ́ Gídíónì, Ísírẹ́lì wà ní àlàáfíà fún ogójì ọdún.

29. Jerub-Báálì ọmọ Jóásìa padà lọ láti máa gbé ní ìlú rẹ̀.

30. Àádọ́rin ọmọ ni ó bí, nítorí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìyàwó.

31. Àlè rẹ̀, tó ń gbé ní Ṣékémù, pàápàá bí ọmọkùnrin kan fún un tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní Ábímélékì.

32. Gídíónì ọmọ Jóásì kú ní ògbólógbó ọjọ́ rẹ̀, ó sì pọ̀ ní ọjọ́ orí, wọ́n sì sin-ín sí ibojì baba rẹ̀ ní Ófírà ti àwọn ará Ábíésérì.

33. Láìpẹ́ jọjọ lẹ́yìn ikú Gídíónì ni àwọn ará Ísírẹ́lì ṣe àgbérè tọ Báálì lẹ́yìn, wọ́n fi Báál-Beriti ṣe òrìṣà wọn.

34. Wọn kò sì rántí Olúwa Ọlọ́run wọn, ẹni tí ó gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta wọn gbogbo tí ó wà ní gbogbo àyíká wọn.

35. Wọ́n kùnà láti fi inú rere hàn sí ìdílé Jérú-Báálì (èyí ni Gídíónì) fún gbogbo ore tí ó ṣe fún wọn.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 8