Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 8:12-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ṣébà àti Ṣálímúnà, àwọn ọba Mídíánì méjèèjì sá, ṣùgbọ́n Gídíónì lépa wọn ó sì mú wọn, ó run gbogbo ogun wọn.

13. Gídíónì ọmọ Jóásì gba ọ̀nà ìgòkè Hérésì padà sẹ́yìn láti ojú ogun.

14. Ó mú ọ̀dọ́mọkùnrin kan ará Ṣúkótì, ó sì béèrè àwọn ìbéèrè ní ọwọ́ rẹ̀, ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì kọ orúkọ àwọn ìjòyè Ṣúkótì mẹ́tadínlọ́gọ́rin (77) fún un tí wọ́n jẹ́ àgbààgbà ìlú náà.

15. Nígbà náà ni Gídíónì wá ó sọ fún àwọn ọkùnrin Ṣúkótì pé, “Ṣébà àti Sálímúnà nìwọ̀nyí nípa àwọn tí ẹ̀yin fi mí ṣẹ̀fẹ̀ nígbà tí ẹ wí pé, ‘Ṣé ó ti ṣẹ́gun Ṣébà àti Ṣálímúnà? Èéṣe tí àwa ó fi fún àwọn ọmọ ogun rẹ tí ó ti rẹ̀ ní oúnjẹ?’ ”

16. Ó mú àwọn àgbààgbà ìlú náà, ó sì fi kọ́ àwọn Ṣúkótì lọ́gbọ́n nípa jíjẹ wọ́n níyà pẹ̀lú àwọn ẹ̀gún aṣálẹ̀ àti ẹ̀gún ọ̀gàn.

17. Ó wọ ilé ìṣọ́ Péníélì, ó sì pa àwọn ọkùnrin ìlú náà.

18. Gídíónì bi Ṣébà àti Ṣálímúnà pé, “Irú ọkùnrin tí ẹ pa ní Tábórì, bá wo ni wọ́n ṣe rí?”“Àwọn ọkùnrin náà dàbí rẹ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dàbí ọmọ ọba,” ní ìdáhùn wọn.

19. Gídíónì dáhùn pé, “Arákùnrin mi ni wọ́n, àwọn ọmọ ìyá mi. Mo fi Olúwa búra, bí ó bá ṣe pé ẹ dá ẹ̀mí wọn sí, èmi náà ò ní pa yín.”

20. Ó yí padà sí Jétérì, ọmọ rẹ̀ tí ó dàgbà jùlọ, ó wí fún un pé, “Pa wọ́n!” Ṣùgbọ́n Jétérì kò fa idà rẹ̀ yọ láti pa wọ́n nítorí ó jẹ́ ọ̀dọ́mọdé ẹ̀rù sì bà á láti pa wọ́n.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 8