Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 6:4-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Wọn yóò tẹ̀dó sí orí ilẹ̀ náà, wọn a sì bá irúgbìn wọ̀nyí jẹ́ títí dé Gásà, wọn kì í sì í fi ohun alààyè kankan ṣílẹ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kìbáà ṣe àgùntàn, màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

5. Wọn a máa wá pẹ̀lú ohun ọ̀sìn wọn àti àwọn àgọ́ wọn, wọn a sì dàbí eṣú nítorí i púpọ̀ wọn. Ènìyàn kò sì lè ka iye àwọn ènìyàn náà bí ni àwọn ẹran ọ̀sìn, wọ́n pọ̀ débi pé wọn kò ṣe é kà ní iye, wọn a bo ilẹ̀ náà wọn a sì jẹ ẹ́ run.

6. Àwọn ará Mídíánì sì pọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lójú, wọ́n sọ wọ́n di òtòsì àti aláìní, fún ìdí èyí wọ́n ké pe Olúwa nínú àdúrà fún ìrànlọ́wọ́.

7. Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ké pe Olúwa nítorí àwọn ará Mídíánì.

8. Olúwa fi etí sí igbe wọn, ó sì rán wòlíì kan sí wọn. Ẹni tí ó wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: mo mú yín gòkè ti Éjíbítì wá, láti oko ẹrú.

9. Mo gbà yín kúrò nínú agbára Éjíbítì àti kúrò ní ọwọ́ gbogbo àwọn aninilára yín. Mo lé wọn kúrò ní iwájú yín, mo sì fi ilẹ̀ wọn fún yín.

10. Mo wí fún un yín pé, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín: ẹ má ṣe sin àwọn òrìṣà àwọn ará Ámórì, ní ilẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin ń gbé. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọ́ràn sí ohun tí mo sọ.”

11. Ní ọjọ́ kan ańgẹ́lì Olúwa wá, ó sì jókòó ní abẹ́ igi óákù ófírà èyí ti ṣe ti Jóásìu ará Ábíésérì, níbi tí Gídíónì ọmọ rẹ̀ ti ń lu ọkà jéró, níbi ìpọn ọtí wáìnì láti fi pamọ́ kúrò níwájú àwọn ará Mídíánì.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 6