Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 6:19-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Gídíónì sì yára wọ ilé lọ, ó sì pa ọ̀dọ́ ewúrẹ́ kan, wọ́n sì ṣè é, ó sì mú ìyẹ̀fun ìyẹ̀fun éfà kan (èyí tó lítà méjìlélógún) ó fi ṣe àkàrà (àkàrà) àìwú. Ó gbé ẹran náà sínú agbọ̀n ṣùgbọ́n ó fi ọbẹ̀ rẹ̀ sínú ìkòkò, ó gbé wọn jáde tọ ańgẹ́lì náà wá bí ọrẹ lábẹ́ igi óákù.

20. Ańgẹ́lì Olúwa náà sì wí fún un pé, “Gbé ẹran náà àti àkàrà àìwú náà, sí orí àpáta yìí, kí o sì da omi ọbẹ̀ rẹ̀ sí orí rẹ̀.” Gídíónì sì ṣe bẹ́ẹ̀.

21. Ańgẹ́lì Olúwa sì fi orí ọ̀pá tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀ kan ẹran àti àkàrà àìwú náà. Iná sì jáde láti inú àpáta, ó sì jó ẹran àti àkàrà náà, kò sì rí ańgẹ́lì náà mọ́.

22. Nígbà tí Gídíónì sì ti mọ̀ dájúdájú pé ańgẹ́lì Olúwa ni, ó ké wí pé, “Háà! Olúwa Ọlọ́run alágbára! Mo ti rí ańgẹ́lì Olúwa ní ojú korojú!”

23. Ṣùgbọ́n Olúwa wí fún un pé, “Àlàáfíà! Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ kì yóò kú.”

24. Báyìí ni Gídíónì mọ pẹpẹ kan fún Olúwa níbẹ̀, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní “Àlàáfíà ni Olúwa.” Ó sì wà ní Ófírà ti Ábíésérì títí di òní.

25. Ní òru ọjọ́ náà Olúwa wí fún un pé, mú akọ màlúù bàbá rẹ kejì láti inú agbo, akọ màlúù ọlọ́dún méje. Wó pẹpẹ Báálì baba rẹ lulẹ̀, kí o sì fọ́ ọ̀pá Áṣírà tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.

26. Lẹ́yìn èyí kí o wá mọ pẹpẹ èyí tí ó yẹ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ lórí òkè yìí. Kí o lọ́ igi Áṣírà tí o ké lulẹ̀, kí o fi akọ màlúù kejì rú ẹbọ sísun sí Olúwa.

27. Gídíónì mú mẹ́wàá nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì ṣe bí Olúwa ti pàṣẹ fún un ṣùgbọ́n, nítorí ó bẹ̀rù àwọn ará ilé bàbá rẹ̀ àti àwọn ènìyàn ìlú náà kò ṣe é ní ọ̀sán, òru ni ó ṣe.

28. Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ kejì mọ́, tí àwọn ènìyàn ìlú náà jí, wọ́n rí i pé àti fọ́ pẹpẹ Báálì àti pé a ti bẹ́ igi òpó Áṣírà tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, a sì ti fi akọ màlúù kejì rúbọ lóríi pẹpẹ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ.

29. Àwọn ènìyàn ìlú náà bi ara wọn wí pé, “Ta ni ó ṣe èyí?”Lẹ́yìn tí wọn fara balẹ̀ ṣe ìwádìí, wọ́n gbọ́ wí pé, “Gídíónì ọmọ Jóásì ni ó ṣe é.”

30. Àwọn ọkùnrin ìlú náà sì wí fún Jóásì wí pé, “Mú ọmọ rẹ jáde wá. Ó ní láti kú nítorí pé ó ti wó pẹpẹ Báálì lulẹ̀ ó sì ti ké òpó Áṣírà tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.”

Ka pipe ipin Onídájọ́ 6