Àwọn ọkùnrin ìlú náà sì wí fún Jóásì wí pé, “Mú ọmọ rẹ jáde wá. Ó ní láti kú nítorí pé ó ti wó pẹpẹ Báálì lulẹ̀ ó sì ti ké òpó Áṣírà tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.”