Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 6:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì tún ṣe ohun tí ó burú ní ojú Olúwa, Ó sì fi wọ́n lé àwọn ará Mídíánì lọ́wọ́ fún ọdún méje.

2. Agbára àwọn ará Mídíánì sì pọ̀ púpọ̀ lórí àwọn Ísírẹ́lì, wọ́n sì hùwà ipá sí wọn, nítorí ìdí èyí, àwọn Ísírẹ́lì sá lọ sí àwọn orí òkè, wọ́n sì kọ́ àgọ́ fún ara wọn nínú ihò àpáta, àti nínú ọ̀gbun àti ní ibi agbára nínú àpáta.

3. Ní ìgbàkúgbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ti gbin ọ̀gbìn wọn, àwọn ará Mídíánì, àwọn ará Ámélékì àti àwọn ará ìlà oòrùn mìíràn yóò wá láti bá wọn jà.

4. Wọn yóò tẹ̀dó sí orí ilẹ̀ náà, wọn a sì bá irúgbìn wọ̀nyí jẹ́ títí dé Gásà, wọn kì í sì í fi ohun alààyè kankan ṣílẹ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kìbáà ṣe àgùntàn, màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 6