Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 5:23-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. ‘Ẹ fi Mérósì,’ bú ni ańgẹ́lì Olúwa wí.‘Ẹ fi àwọn ènìyàn inú rẹ̀ gégùn ún kíkorò,nítorí wọn kò wá sí ìrànlọ́wọ́ OLÚWÁ,láti dojúkọ àwọn alágbára.’

24. “Alábùkún jùlọ nínú àwọn ọmọ obìnrin ni Jáélì,aya Hébérì ará Kénì,alábùkún jùlọ nínú àwọn obìnrin tí ń gbé inú àgọ́.

25. Ó bèèrè omi, ó fún un ní wàrà;ó fi àwo iyebíye tí ó yẹ fún àwọn ọlọ́la fún un ni wàrà dídì.

26. Ó na ọwọ́ rẹ̀ mú ìṣó àgọ́,ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú òòlù awọ gbẹ́nàgbẹ́nà.Ó kan Ṣísérà mọ́lẹ̀ pẹ̀lú òòlù ọwọ́ rẹ̀, ó fọ́ ọ ní orí,Ó kàn ẹ̀bátí rẹ̀ mọ́lẹ̀ sinsiǹ.

27. Ní ẹṣẹ̀ rẹ̀, ó wólẹ̀ó ṣubú; ó dúbúlẹ̀.Ní ẹṣẹ̀ rẹ̀, ó wó lulẹ̀;ní ibi tí ó gbé wólẹ̀ sí, níbẹ̀ náà ni ó ṣubú kú.

28. “Ìyá Ṣísérà yọjú láti ojú fèrèsé,ó sì kígbe, ó kígbe ní ojú fèrèsé ọlọ́nà pé,‘Èése tí kẹ̀kẹ́ ẹsin rẹ fi pẹ́ bẹ́ẹ̀ láti dé?Èéṣe tí ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ẹsin rẹ̀ fí dúró lẹ́yìn?’

29. Àwọn amòye obìnrin rẹ̀ dá a lóhùn;àní òun náà pẹ̀lú ti dá ara rẹ̀ lóhùn pé,

30. ‘Wọn kò ha ti rí wọn, wọn kò ha ti pín ìkógun bọ̀ fún olúkálùkù:ọmọbìnrin kan tàbí méjì fún ọkùnrin kan,fún Ṣísérà ìkógun aṣọ aláràbarà,ìkógun aṣọ aláràbarà àti ọlọ́nà,àwọn aṣọ ọlọ́nà iyebíye fún ọrùn mi,gbogbo wọn tí a kó ní ogun?’

31. “Bẹ́ẹ̀ ni kí ó jẹ́ kí gbogbo àwọn ọ̀ta rẹ kí ó ṣègbé Olúwa!Ṣùgbọ́n jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ ọ ràn bí oòrùn.nígbà tí ó bá yọ nínú agbára rẹ̀.”Ilẹ̀ náà sì simi ní ogójì ọdún

Ka pipe ipin Onídájọ́ 5