Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 3:15-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ṣùgbọ́n nígbà tí Ísírẹ́lì tún ké pe Olúwa, Olúwa rán olùgbàlà sí wọn, Éhúdù ẹni tí ń lo ọwọ́ òsì, ọmọ Gérà ti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì. Éhúdù ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń fi owó orí wọn rán sí Égílónì olú ìlú Móábù ní ọdọọdún fún ọdún mẹ́rìndínlógún.

16. Ṣùgbọ́n kí ó tó lọ ní ọdún yìí Éhúdù ti ṣe idà mímú olójú méjì kan tí gígùn rẹ̀ fẹ́ ẹ̀ tó ẹṣẹ̀ kan ààbọ̀, ó sì fi pamọ́ sínú àwọn aṣọ rẹ̀ tí ó so mọ́ itan rẹ̀ ọ̀tún.

17. Éhúdù gbé owó orí náà lọ bí ó ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ ó sì fi fún Égílónì ẹni tí ó sanra púpọ̀.

18. Lẹ́yìn tí ó ti fi ẹ̀bùn náà fún ọba tan, ó rán àwọn tí ó kó ẹrú náà wá lọ sí ọ̀nà wọn.

19. Ṣùgbọ́n ní ẹ̀yìn odi ìlú níbi tí wọ́n ti gbẹ́ òkúta, òun padà ṣẹ́yìn, ó sì wí fún ọba pé, “Mo ní ọ̀rọ̀ àsírí láti bá ọ sọ.”Ọba sì wí pé “Ẹ dákẹ́!” Gbogbo àwọn tí ń sọ sì jáde síta kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.

20. Éhúdù lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ níbi tí ó ti jókòó ní iyàrá ìtura rẹ̀, Éhúdù sì wí fún-un pé: “Mo ní ọ̀rọ̀ kan fún ọ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” Bí ọba sì ti dìde ní orí ìtẹ́ rẹ̀,

21. Éhúdù fi ọwọ́ òsì rẹ̀ yọ idà láti ibi itan ọ̀tún rẹ̀ ó sì fi gún ọba nínú ikùn rẹ̀.

22. Àti idà àti èèkù rẹ̀ sì wọlé ó sì yọ ní ẹ̀yìn rẹ̀. Éhúdù kò yọ idà náà, ọ̀rá sì bo idà náà.

23. Éhúdù ti àwọn ìlẹ̀kùn ní àtì-sínú òun sì bá yàrá òkè jáde, ó sì sálọ.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 3