Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 21:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì ti búra ní Mísípà pé: “Kò sí ẹnìkan nínú wa tí yóò fi ọmọ obìnrin rẹ̀ fún ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ní ìyàwó.”

2. Àwọn ènìyàn náà lọ sí Bẹ́tẹ́lì: ilé Ọlọ́run, níbi tí wọ́n jókòó níwájú Ọlọ́run títí di àṣálẹ́, wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sunkún kíkorò.

3. Wọ́n sunkún wí pé, “Háà! Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, èéṣe tí nǹkan yìí fi ṣẹlẹ̀ sí Ísírẹ́lì? Èéṣe tí ẹ̀yà kan yóò fi run nínú Ísírẹ́lì lónìí?”

4. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì àwọn ènìyàn náà mọ pẹpẹ kan wọ́n sì rúbọ ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ ìrẹ́pọ̀ (ìbáṣepọ̀, àlàáfíà).

5. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì béèrè wí pé, “Èwo nínú ẹ̀yà Ísírẹ́lì ni ó kọ̀ láti péjọ ṣíwájú Olúwa?” Torí pé wọ́n ti fi ìbúra ńlá búra pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti péjọ níwájú Olúwa ní Mísípà pípa ni àwọn yóò pa á.

6. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì banújẹ́ fún àwọn arákùnrin wọn, àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì. Wọ́n wí pé, “A ti ké ẹ̀yà kan kúrò lára Ísírẹ́lì lónìí.”

Ka pipe ipin Onídájọ́ 21