8. Jóṣúà ọmọ Núnì ìránṣẹ́ Olúwa kú ní ẹni àádọ́fà ọdún (110).
9. Wọ́n sì sìnkú rẹ̀ sí ààlà ilẹ̀ ìní rẹ̀ ní Tímínátì-Hérésì ní ilẹ̀ òkè Éfúráímù ní àríwá òkè Gásà.
10. Ní ìgbẹ̀yìn, gbogbo ìran náà sì kú; àwọn ìran tí ó tẹ̀lé wọn kò sì sin Olúwa nítorí wọn kò mọ Olúwa bẹ́ẹ̀ ni wọn kò mọ ohun tí Olúwa ṣe fún Ísírẹ́lì.
11. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe ohun tí ó burú níwájú Olúwa, wọ́n sì ń sin òrìṣà Bálímù.
12. Wọ́n kọ Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn sílẹ̀ ẹni tí ó mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì, wọ́n ń tọ àwọn òrìṣà lẹ́yìn, wọ́n sì ń sin àwọn oríṣìíriṣí òrìṣà àwọn ará ilẹ̀ ibi tí wọ́n ń gbé, wọ́n sì mú Olúwa bínú.
13. Nítorí tí wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀ àti nítorí pé wọ́n ń sin Báálì àti Ásítarótù.
14. Nínú ìbínú rẹ̀ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Olúwa fi wọ́n lé àwọn akónisìn lọ́wọ́ tí ó kó wọn ní ẹrú, tí ó sì bà wọ́n jẹ́. Ó sì tà wọ́n fún àwọn ọ̀ta wọn tí ó yí wọn ká àwọn ẹni tí wọn kò le dúró dè láti kọ ojú ìjà sí.
15. Nígbà-kí-ìgbà tí àwọn Ísírẹ́lì bá jáde lọ sí ojú ogun láti jà, ọwọ́ Olúwa sì wúwo ní ara wọn, àwọn ọ̀ta a sì borí wọn, àní gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún wọn, wọ́n sì wà nínú ìpọ́njú púpọ̀.