Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 19:4-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Àna rẹ̀, baba ọmọbìnrin náà rọ̀ ọ́, ó sì borí rẹ̀ láti dá a dúró fún ìgbà díẹ̀, òun sì dúró fún ọjọ́ mẹ́ta, ó ń jẹ, ó ń mu, ó sì ń sùn níbẹ̀.

5. Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n dìde ní òwúrọ̀ kùtùkùtù òun sì múra láti padà lọ, ṣùgbọ́n baba ọmọbìnrin náà wí fún àna rẹ̀ pé, “Fi ohun jíjẹ díẹ̀ gbé inú ró nígbà náà kí ìwọ máa lọ.”

6. Àwọn méjèèjì sì jùmọ̀ jókòó wọn láti jọ jẹun àti láti jọ mu. Lẹ́yìn èyí ni baba ọmọbìnrin wí pé, “Jọ̀wọ́ dúró ní alẹ́ yìí kí o sì gbádùn ara rẹ.”

7. Nígbà tí ọkùnrin náà dìde láti máa lọ, baba ìyàwó rẹ̀ rọ̀ ọ́, torí náà ó sùn níbẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ náà.

8. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ karùn ún nígbà tí ó dìde láti lọ, baba ọmọbìnrin wí pé, “Fi oúnjẹ gbé ara ró. Dúró de ọ̀sán!” Àwọn méjèèjì sì jùmọ̀ jọ jẹun.

9. Nígbà tí ọkùnrin náà, pẹ̀lú àlè àti ìránṣẹ́ rẹ̀, dìde láti máa lọ, àna rẹ̀, baba ọmọbìnrin náà ní, “Wò ó ilẹ̀ ti ń ṣú lọ, dúró níbí, ọjọ́ ti lọ. Dúró kí o sì gbádùn ara rẹ. Ìwọ lè jí ní àárọ̀ kùtùkùtù ọ̀la kí ìwọ sì máa lọlé.”

10. Ṣùgbọ́n nítorí pé òun kò fẹ́ dúró mọ́ níbẹ̀ ní òru náà ọkùnrin náà kúrò ó sì gba ọ̀nà Jébúsì: ọ̀nà Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ méjèèjì tí ó fi dì í ní gàárì àti àlè rẹ̀.

11. Nígbà tí wọ́n súnmọ́ Jébúsì tí ilẹ̀ ti fẹ́ ṣú tan, ìránṣẹ́ náà sọ fún ọ̀gá rẹ̀ pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a dúró ní ìlú yìí tí í ṣe ti àwọn ará Jébúsì kí a sì sùn níbẹ̀.”

12. Ọ̀gá rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Rárá o, àwa kì yóò wọ ìlú àwọn àjèjì, àwọn tí olùgbé ibẹ̀ kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, a ó ò dé Gíbíà.”

13. Ó fi kún un pé, ẹ wá ẹ jẹ́ kí a gbìyànjú kí a dé Gíbíà tàbí Rámà kí a sùn ní ọ̀kan nínú wọn.

14. Wọ́n sì tẹ̀ṣíwájú nínú ìrìnàjò wọn, oòrùn wọ̀ bí wọ́n ti súnmọ́ Gíbíà tí ṣe ti àwọn Bẹ́ńjámínì.

15. Wọ́n yípadà wọ́n lọ sí inú ìlú náà láti wọ̀ ṣíbẹ̀ ní òru náà, wọ́n lọ wọ́n sì jókòó níbi gbọ̀ngàn ìlú náà, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó gbà wọ́n sínú ilé rẹ̀ láti wọ̀ sí.

16. Ní alẹ́ ọjọ́ náà ọkùnrin arúgbó kan láti àwọn òkè Éfúráímù, ṣùgbọ́n tí ń gbé ní Gíbíà (ibẹ̀ ni àwọn ènìyàn Bẹ́ńjámínì ń gbé) ń ti ibi iṣẹ́ rẹ̀ bọ̀ láti inú oko.

17. Nígbà tí ó wòkè ó rí arìnrìnàjò náà ní gbọ̀ngàn ìlú náà, ọkùnrin arúgbó yìí bi í léèrè pé, “Níbo ni ò ń lọ? Níbo ni o ti ń bọ̀?”

Ka pipe ipin Onídájọ́ 19