Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 17:9-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Míkà bi í pé, “Níbo ni ó ti ń bọ̀?”Ó dáhùn pé, “Ọmọ Léfì ni mí láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Júdà, mo sì ń wá ibi tí èmi yóò máa gbé.”

10. Míkà sì sọ fún un wí pé, “Dúró lọ́dọ̀ mi (máa bá mi gbé) kí ìwọ sì jẹ́ baba mi àti àlùfáà fún mi, èmi ó sì máa fún ọ ní ṣékélì mẹ́wàá fàdákà ní ọdọọdún, pẹ̀lú aṣọ àti oúnjẹ rẹ̀.”

11. Ọmọ Léfì náà sì gbà láti máa bá a gbé, ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì dàbí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀.

12. Nígbà náà ni Míkà ya ará Léfì náà sí mímọ́, ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì di àlùfáà rẹ̀, ó sì ń gbé ilé rẹ̀.

13. Míkà sì wí pé, “Báyìí, èmi mọ̀ pé Olúwa yóò ṣe mi ní oore nítorí pé mo ní ọmọ Léfì ní àlùfáà mi.”

Ka pipe ipin Onídájọ́ 17