Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 15:6-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Nígbà tí àwọn Fílístínì béèrè pé, “Ta ni ó ṣe èyí?” Wọ́n dá wọn lóhùn pé, “Sámúsónì ará Tímínà ni, nítorí o gba ìyàwó rẹ̀ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀.”Nítorí náà àwọn Fílístínì lọ wọ́n sì ṣun obìnrin náà àti baba rẹ̀.

7. Sámúsónì sọ fún un pé, “Nítorí pé ẹ̀yin ṣe èyí, èmi kò dẹṣẹ̀ (dúró) títí èmi yóò fi gbẹ̀ṣan mi lára yín.”

8. Ó kọ lù wọ́n pẹ̀lú ìbínú àti agbára ńlá, ó sì pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn. Lẹ́yìn náà ni ó lọ, ó sì dúró nínú ihò àpáta kan nínú àpáta Étamù.

9. Àwọn ará Fílístínì sì dìde ogun sí Júdà, wọ́n ti tan ara wọn ká sí agbégbé Léhì.

10. Àwọn ọkùnrin Júdà sì bèèrè pé, “Èéṣe tí ẹ fi wá gbógun tì wá?”Ìdáhùn wọn ni pé, “Awá láti mú Sámúsónì ní ìgbékùn, kí a ṣe sí i bí òun ti ṣe sí wa.”

11. Nígbà náà ni ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3000) ọkùnrin láti Júdà sọ̀kalẹ̀ lọ sí ihò àpáta nínú àpáta Étamù, wọ́n sì sọ fún Sámúsónì pé, “Kò ti yé ọ pé àwọn Fílístínì ní ń ṣe alákóṣo lórí wa? Kí ni o ṣe sí wa?”Òun sì dáhùn pé, “Ohun tí wọ́n ṣe sí mi ni èmi náà ṣe sí wọn.”

12. Wọ́n wí pé, “Àwa wá láti dè ọ́, kí a sì fi ọ́ lé àwọn Fílístínì lọ́wọ́.”Sámúsónì wí pé, “Ẹ búra fún mi pé, ẹ̀yin kì yóò fúnra yín pa mí.”

13. “Àwá gbà,” ni ìdáhùn wọn. “Àwa yóò kàn dè ọ́, awa yóò sì fi ọ́ lé wọn lọ́wọ́, àwa kì yóò pa ọ́.” Wọ́n sì dé pẹ̀lú okùn túntún méjì, wọ́n sì mú u jáde wá láti ihò àpáta náà.

14. Bí ó ti sún mọ́ Léhì, àwọn Fílístínì ń pariwo bí wọ́n ṣe ń tò bọ̀. Ẹ̀mí Olúwa bà lé e pẹ̀lú agbára. Àwọn okùn ọwọ́ rẹ̀ dàbí òwú tí ó jóná, ìdè ọwọ́ rẹ̀ já kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.

15. Nígbà tí ó rí egungun àgbọ̀n ìṣàlẹ̀ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ túntún kan, ó mú un, ó sì fi pa ẹgbẹ̀rún ọkùnrin.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 15