Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 15:14-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Bí ó ti sún mọ́ Léhì, àwọn Fílístínì ń pariwo bí wọ́n ṣe ń tò bọ̀. Ẹ̀mí Olúwa bà lé e pẹ̀lú agbára. Àwọn okùn ọwọ́ rẹ̀ dàbí òwú tí ó jóná, ìdè ọwọ́ rẹ̀ já kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.

15. Nígbà tí ó rí egungun àgbọ̀n ìṣàlẹ̀ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ túntún kan, ó mú un, ó sì fi pa ẹgbẹ̀rún ọkùnrin.

16. Sámúsónì sì wí pé,“Pẹ̀lú egungun àgbọ̀n ìsàlẹ̀ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kanMo sọ wọ́n di òkìtì kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.Pẹ̀lú egungun àgbọ̀n ìsàlẹ̀ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kanMo ti pa ẹgbẹ̀rún ọkùnrin.”

17. Nígbà tí ó dákẹ́ ọ̀rọ̀ ísọ, ó ju egungun àgbọ̀n ìṣàlẹ̀ náà nù, wọ́n sì pe ibẹ̀ ní Ramati-Léhì (ìtúmọ̀ rẹ̀ jẹ́ egungun àgbọ̀n ìṣàlẹ̀ pa).

18. Nítorí tí òǹgbẹ gbẹ ẹ́ gidigidi, ó ké pe Olúwa, wí pé, “Ìwọ ti fún ìránṣẹ́ ní ìṣẹ́gun tí ó tóbi yìí. Ṣé èmi yóò ha kú pẹ̀lú òǹgbẹ, kí èmi sì ṣubú sí ọwọ́ àwọn aláìkọlà ènìyàn?”

19. Nígbà náà ni Ọlọ́run la kòtò ìṣun omi tí ó wà ní Léhì, omi sì tú jáde láti inú rẹ̀. Nígbà tí Sámúsónì mú mi tan, agbára rẹ̀ sì padà, ọkàn sì sọjí, fún ìdí èyí wọ́n pe ìṣun omi náà ni. Ẹni Hákkò rẹ (oríṣun ẹni tí ó pe Ọlọ́run) èyí tí ó sì wà ní Léhì di òní.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 15