Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 14:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà kan Sámúsónì gòkè lọ sí Tímínà níbẹ̀ ni ó ti rí ọmọbìnrin Fílístínì kan.

2. Nígbà tí ó darí (padà sílé) dé, ó sọ fún àwọn òbí rẹ̀ (baba àti ìyá rẹ̀) pé, “Mo rí obìnrin Fílístínì kan ní Tímínà: báyìí ẹ fẹ́ ẹ fún mi bí aya mi”

3. Baba àti ìyá rẹ̀ dáhùn pé, ṣé kò sí obìnrin tí ó dára tí ó sì tẹ́ ọ lọ́rùn ní àárin àwọn ìbátan rẹ, tàbí láàárin gbogbo àwọn ènìyàn wa? Ṣé ó di túlàsì fún ọ láti lọ sí àárin àwọn Fílístínì aláìkọlà kí o tó fẹ́ ìyàwó?Ṣùgbọ́n Sámúsónì wí fún baba rẹ̀ pé, “Fẹ́ ẹ fún mi torí pé inú mi yọ́ síi púpọ̀ púpọ̀.”

4. (Àwọn òbí rẹ̀ kò mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Olúwa ni nǹkan yìí ti wá, ẹni tí ń wá ọ̀nà àti bá Fílístínì jà; nítorí àwọn ni ń ṣe àkóso Ísírẹ́lì ní àkókò náà.)

5. Sámúsónì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Tímínà òun àti bàbá àti ìyá rẹ̀. Bí wọ́n ṣe ń súnmọ́ àwọn ọgbà àjàrà tí ó wà ní Tímínà, láìrò tẹ́lẹ̀, ọ̀dọ́ kìnnìún kan jáde síta tí ń ké ramúramù bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.

6. Ẹ̀mí Olúwa sì bà lé e pẹ̀lú agbára tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi fa kìnnìún náà ya pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀ lásán bí ẹní ya ọmọ ewúrẹ́, ṣùgbọ́n òun kò sọ ohun tí ó ṣe fún baba tàbí ìyá rẹ̀.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 14