Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 13:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì tún ṣe ohun tí ó burú ní ojú Olúwa, Olúwa sì fi wọ́n lé àwọn ará Fílístínì lọ́wọ́ fún ogójì (40) ọdún.

2. Ọkùnrin ará Sórà kan wà, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Mánóà láti ẹ̀yà Dánì. Aya rẹ̀ yàgàn kò sì bímọ.

3. Ańgẹ́lì Olúwa fara han obìnrin náà, ó sì wí fún un pé, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ yàgàn, ìwọ kò sì tíì bímọ, ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan.

4. Báyìí rí i dájúdájú pé ìwọ kò mu wáìnì tàbí ọtí líle kankan àti pé ìwọ kò jẹ ohun aláìmọ́ kankan,

5. nítorí ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan. Má se fi abẹ kan orí rẹ̀, nítorí pé Násírì (ẹni ìyàsọ́tọ̀) Ọlọ́run ni ọmọ náà yóò jẹ́, ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún Ọlọ́run láti ọjọ́ ìbí rẹ̀. Òun ni yóò bẹ̀rẹ̀ ìdáǹdè àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní ọwọ́ àwọn ará Fílístínì.”

6. Nígbà náà ni obìnrin náà tọ ọkọ rẹ̀ lọ, o sì sọ fún un wí pé, “Èniyàn Ọlọ́run kan tọ̀ mí wá. Ó jọ ańgẹ́lì Ọlọ́run, ó bà ènìyàn lẹ́rù gidigidi. Èmi kò béèrè ibi tí ó ti wá, òun náà kò sì sọ orúkọ rẹ̀ fún mi.

7. Ṣùgbọ́n ó sọ fún mi wí pé, ‘Ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan, fún ìdí èyí, má ṣe mu wáìnì tàbí àwọn ọtí líle mìíràn bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ má se jẹ ohunkóhun tí í ṣe aláìmọ́, nítorí pé Násírì Ọlọ́run ni ọmọ náà yóò jẹ́ láti ọjọ́ ìbí rẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.’ ”

8. Nígbà náà ni Mánóà gbàdúrà sí Olúwa wí pé, “Háà Olúwa, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ènìyàn Ọlọ́run tí ìwọ rán sí wa padà tọ̀ wá wá láti kọ́ wa bí àwa yóò ti ṣe tọ́ ọmọ tí àwa yóò bí náà.”

9. Ọlọ́run fetí sí ohùn Mánóà, ańgẹ́lì Ọlọ́run náà tún padà tọ obìnrin náà wá nígbà tí ó wà ní oko: Ṣùgbọ́n ọkọ rẹ̀ Mánóà kò sí ní ọ̀dọ̀ rẹ̀.

10. Nítorí náà ni obìnrin náà ṣe yára lọ sọ fún ọkọ rẹ̀ pé, “Ọkùnrin tí ó fara hàn mí ní ọjọ́sí ti tún padà wá.”

11. Mánóà yára dìde, ó sì tẹ̀lé aya rẹ̀, nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ ọkùnrin náà ó ní, “Ǹjẹ́ ìwọ ni o bá obìnrin yìí sọ̀rọ̀?”Ọkùnrin náà dáhùn pé “Èmi ni.”

Ka pipe ipin Onídájọ́ 13