nítorí ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan. Má se fi abẹ kan orí rẹ̀, nítorí pé Násírì (ẹni ìyàsọ́tọ̀) Ọlọ́run ni ọmọ náà yóò jẹ́, ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún Ọlọ́run láti ọjọ́ ìbí rẹ̀. Òun ni yóò bẹ̀rẹ̀ ìdáǹdè àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní ọwọ́ àwọn ará Fílístínì.”