Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 11:32-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

32. Jẹ́fítà sì jáde lọ láti bá àwọn ará Ámónì jagun, Olúwa sì fi wọ́n lé e lọ́wọ́.

33. Òun sì ṣẹ́gun wọn, ó sì pa wọ́n ní àpa tán láti Áróérì títí dé agbègbè Mínítì, ó jẹ́ ogún ìlú, títí dé Abeli-Kérámímù. Báyìí ni Ísírẹ́lì ti ṣẹ́gun àwọn ará Ámónì.

34. Nígbà tí Jẹ́fítà padà sí ilé rẹ̀ ní Mísípà, wò ó, ọmọ rẹ̀ obìnrin ń jáde bọ̀ wá pàdé rẹ̀ pẹ̀lú taboríìnì àti ijó. Òun ni ọmọ kan ṣoṣo tí ó ní: kò ní ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mìíràn yàtọ̀ sí òun nìkan.

35. Ní ìgbà tí ó rí i ó fa aṣọ rẹ̀ ya ní ìbànújẹ́, ó sì ké wí pé, “Háà! Ọ̀dọ́mọbìnrin mi, ìwọ fún mi ní ìbànújẹ́ ọkàn ìwọ sì rẹ̀ mí sílẹ̀ gidigidi, nítorí pé èmi ti ya ẹnu mi sí Olúwa ní ẹ̀jẹ́, èmi kò sì le ṣẹ́ ẹ̀jẹ́ mi.”

36. Ọmọ náà sì dáhùn pé, “Baba mi bí ìwọ bá ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa, ṣe sí mi gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ, ní báyìí tí Olúwa ti gba ẹ̀ṣan fún ọ lára àwọn ọ̀ta rẹ, àwọn ará Ámónì.

37. Ṣùgbọ́n yọ̀ǹda ìbéèrè kan yìí fún mi, gbà mí láàyè oṣù méjì láti rìn ká orí àwọn òkè, kí n ṣunkún pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ mi torí mo jẹ́ wúndíá tí n kò sì ní lè ṣe ìgbéyàwó.”

38. Jẹ́fítà dá lóhùn pé, “Ìwọ lè lọ.” Ó sì gbà á láàyè láti lọ fún oṣù méjì. Òun àti àwọn ọmọbìnrin yóòkù lọ sí orí àwọn òkè, wọ́n ṣunkún nítorí pé kì yóò lè ṣe ìgbéyàwó.

39. Lẹ́yìn oṣù méjì náà, ó padà tọ baba rẹ̀ wá òun sì ṣe sí i bí ẹ̀jẹ́ tí ó ti jẹ́. Ọmọ náà sì jẹ́ wúndíá tí kò mọ ọkùnrin rí.Èyí sì bẹ̀rẹ̀ àṣà kan ní Ísírẹ́lì

40. wí pé ní ọjọ́ mẹ́rin láàrin ọdún àwọn obìnrin Ísírẹ́lì a máa lọ láti ṣọ̀fọ̀ àti ṣe ìrántí ọmọbìnrin Jẹ́fítà ti Gílíádì.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 11