Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 11:3-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Jẹ́fità sì sá kúrò lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, ó sì pàgọ́ sí ilẹ̀ Tóbù, ó sì ń gbé níbẹ̀, níbẹ̀ ni àwọn ènìyàn kan ti ń tẹ ofìn lójú para pọ̀ láti máa tẹ̀lé e kiri.

4. Ní àsìkò kan, nígbà tí àwọn ará Ámónì dìde ogun sí àwọn Ísírẹ́lì,

5. Àwọn ìjòyè: aṣíwájú Gílíádì tọ Jẹ́fítà lọ láti pè é wá láti ilẹ̀ Tóbù.

6. Wọ́n wí fún Jẹ́fità wí pé, “Wá kí o sì jẹ́ olórí ogun wa kí a lè kọjú ogun sí àwọn ará Ámónì.”

7. Jẹ́fítà sì dáhùn pé, “Ṣé kì í ṣe pé ẹ kóríra mi tí ẹ sì lé mi kúrò ní ilé baba mi? Kí ló dé tí ẹ fi tọ̀ mí wá báyìí nígbà tí ẹ wà nínú wàhálà?”

8. Àwọn ìjòyè: àgbà Gílíádì dáhùn pé, “Nítorí rẹ̀ ni àwa fi yípadà sí ọ báyìí: tẹ̀lé wa, kí a lè dojú ìjà kọ àwọn ará Ámónì, ìwọ yóò sì jẹ olórí wa àti gbogbo àwa tí ń gbé ní Gílíádì.”

9. Jẹ́fità dáhùn pé, “Bí ẹ̀yin bá mú mi padà láti bá àwọn ará Ámónì jà àti tí Olúwa bá fi wọ́n lé mi lọ́wọ́: ṣe èmi yóò jẹ́ olórí yín nítòótọ́.”

10. Àwọn ìjòyè Gílíádì dáhùn pé, “Àwa fi Olúwa ṣe ẹlẹ́rìí: àwa yóò ṣe ohunkóhun tí o bá wí.”

11. Jẹ́fità sì tẹ̀lé àwọn olóyè Gílíádì lọ, àwọn ènìyàn náà sì fi ṣe olórí àti ọ̀gágun wọn. Jẹ́fità sì tún sọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ti sọ tẹ́lẹ̀ níwájú Olúwa ní Mísípà.

12. Jẹ́fítà sì rán àwọn oníṣẹ́ sí ọba àwọn ará Ámónì pé, “Kí ni ẹ̀ṣùn tí o ní sí wa láti fi kàn wá tí ìwọ fi dojú ìjà kọ ilẹ̀ wa?”

13. Ọba àwọn Ámónì dá àwọn oníṣẹ́ Jẹ́fità lóhùn pé, “Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde ti Éjíbítì wá. Wọ́n gba ilẹ̀ mi láti Ánónì dé Jábókù, àní dé Jọ́dánì, nítorí náà dá wọn padà lọ ní àlàáfíà àti ní pẹ̀lẹ́ kùtù.”

14. Jẹ́fítà sì tún ránṣẹ́ padà sí ọba àwọn ará Ámónì

Ka pipe ipin Onídájọ́ 11