Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 11:19-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. “Nígbà náà ni Ísírẹ́lì rán àwọn oníṣẹ́ sí Síhónì ọba àwọn ará Ámórì, ẹni tí ń ṣe àkóso ní Hésíbónì, wọ́n sì wí fún un pé, ‘Jẹ́ kí a la ilẹ̀ rẹ kọja lọ sí ibùgbé wa.’

20. Ṣùgbọ́n Síhónì kò gba Ísírẹ́lì gbọ́ (kò fọkàn tán an) láti jẹ́ kí ó kọjá. Ó kó gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ jọ, ó sì tẹ̀dó sí Jáhásì láti bá Ísírẹ́lì jagun.

21. “Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì sì fi Síónì àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́, wọ́n sì ṣẹ́gun wọn. Ísírẹ́lì sì gba gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Ámórì tí wọ́n ń gbé ní agbégbé náà,

22. wọ́n gbà gbogbo agbégbé àwọn ará Ámórì tí ó fi dé Jábókù, àti láti aṣálẹ̀ dé Jọ́dánì.

23. “Wàyí o, nígbà tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ti lé àwọn ará Ámórì kúrò níwájú àwọn ènìyàn rẹ̀; Ísírẹ́lì, ẹ̀tọ́ wo ni ẹ ní láti gba ilẹ̀ náà?

24. Ǹjẹ́ ìwọ kì yóò ha gba èyí tí Kémọ́sì òrìṣà rẹ fí fún ọ? Bákan náà àwa yóò gba èyíkéyìí tí Olúwa Ọlọ́run wa fi fún wa.

25. Ǹjẹ́ ìwọ ha sàn jú Bálákì ọmọ Sípórì, ọba Móábù lọ? Ǹjẹ́ òun ha ṣe gbólóhùn aṣọ̀ pẹ̀lú Ísírẹ́lì bí? Tàbí òun dojú ìjà kọ wọ́n rí bí?

26. Fún ọ̀ọ́dúnrún ọdún (300) ni Ísírẹ́lì fi ṣe àtìpó ní Hésíbónì, Áróérì àti àwọn ìgbéríko àti àwọn ìlú tí ó yí Ánónì ká. Èéṣe tí ìwọ kò fi gbà wọ́n padà ní àsìkò náà?

27. Èmi kọ́ ni ó ṣẹ̀ ọ́, ṣùgbọ́n ìwọ ni ó ṣẹ̀ mí nípa kíkógun tọ̀ mí wá. Jẹ́ kí Olúwa olùdájọ́, ṣe ìdájọ́ lónìí láàárin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àwọn ará Ámónì.”

28. Ṣùgbọ́n ọba àwọn Ámónì kò fetí sí iṣẹ́ tí Jẹ́fítà rán síi.

29. Ẹ̀mí Olúwa sì bà lé Jẹ́fítà òun sì la Gílíádì àti Mánásè kọjá. Ó la Mísípà àti Gílíádì kọja láti ibẹ̀, ó tẹ̀ṣíwájú láti bá àwọn ará Ámónì jà.

30. Jẹ́fítà sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa pé, “Bí ìwọ bá fi àwọn ará Ámónì lé mi lọ́wọ́,

31. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jáde láti ẹnu ọ̀nà mi láti wá pàdé mi, nígbà tí èmi bá ń padà bọ̀ ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọmọ Ámónì yóò jẹ́ ti Olúwa, èmi yóò sì fi rúbọ bí ọrẹ ẹbọ ṣíṣun.”

32. Jẹ́fítà sì jáde lọ láti bá àwọn ará Ámónì jagun, Olúwa sì fi wọ́n lé e lọ́wọ́.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 11