Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 11:12-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Jẹ́fítà sì rán àwọn oníṣẹ́ sí ọba àwọn ará Ámónì pé, “Kí ni ẹ̀ṣùn tí o ní sí wa láti fi kàn wá tí ìwọ fi dojú ìjà kọ ilẹ̀ wa?”

13. Ọba àwọn Ámónì dá àwọn oníṣẹ́ Jẹ́fità lóhùn pé, “Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde ti Éjíbítì wá. Wọ́n gba ilẹ̀ mi láti Ánónì dé Jábókù, àní dé Jọ́dánì, nítorí náà dá wọn padà lọ ní àlàáfíà àti ní pẹ̀lẹ́ kùtù.”

14. Jẹ́fítà sì tún ránṣẹ́ padà sí ọba àwọn ará Ámónì

15. ó sì wí fún un pé:“Báyìí ni Jẹ́fítà wí: àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò gba ilẹ̀ Móábù tàbí ilẹ̀ àwọn ará Ámónì.

16. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n jáde kúrò ní Éjíbítì àwọn ọmọ Ísírẹ́lì la ihà kọjá lọ sí ọ̀nà òkun pupa wọ́n sì lọ sí Kádésì.

17. Nígbà náà Ísírẹ́lì rán àwọn oníṣẹ́ sí ọba Édómù pé, ‘Gbà fún wa láti gba ilẹ̀ rẹ̀ kọjá,’ ṣùgbọ́n ọba Édómù kò fetí sí wọn. Wọ́n tún ránṣẹ́ sí ọba Móábù bákan náà òun náà kọ̀. Nítorí náà Ísírẹ́lì dúró sí Kádésì.

18. “Wọ́n rin ihà kọjá, wọ́n pẹ́ àwọn ilẹ̀ Édómù àti ti Móábù sílẹ̀, nígbà tí wọ́n gba apá ìlà oòrùn Móábù, wọ́n sì tẹ̀dó sí apá kejì Ánónì. Wọn kò wọ ilẹ̀ Móábù, nítorí pé ààlà rẹ̀ ni Ánónì wà.

19. “Nígbà náà ni Ísírẹ́lì rán àwọn oníṣẹ́ sí Síhónì ọba àwọn ará Ámórì, ẹni tí ń ṣe àkóso ní Hésíbónì, wọ́n sì wí fún un pé, ‘Jẹ́ kí a la ilẹ̀ rẹ kọja lọ sí ibùgbé wa.’

20. Ṣùgbọ́n Síhónì kò gba Ísírẹ́lì gbọ́ (kò fọkàn tán an) láti jẹ́ kí ó kọjá. Ó kó gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ jọ, ó sì tẹ̀dó sí Jáhásì láti bá Ísírẹ́lì jagun.

21. “Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì sì fi Síónì àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́, wọ́n sì ṣẹ́gun wọn. Ísírẹ́lì sì gba gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Ámórì tí wọ́n ń gbé ní agbégbé náà,

22. wọ́n gbà gbogbo agbégbé àwọn ará Ámórì tí ó fi dé Jábókù, àti láti aṣálẹ̀ dé Jọ́dánì.

23. “Wàyí o, nígbà tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ti lé àwọn ará Ámórì kúrò níwájú àwọn ènìyàn rẹ̀; Ísírẹ́lì, ẹ̀tọ́ wo ni ẹ ní láti gba ilẹ̀ náà?

24. Ǹjẹ́ ìwọ kì yóò ha gba èyí tí Kémọ́sì òrìṣà rẹ fí fún ọ? Bákan náà àwa yóò gba èyíkéyìí tí Olúwa Ọlọ́run wa fi fún wa.

25. Ǹjẹ́ ìwọ ha sàn jú Bálákì ọmọ Sípórì, ọba Móábù lọ? Ǹjẹ́ òun ha ṣe gbólóhùn aṣọ̀ pẹ̀lú Ísírẹ́lì bí? Tàbí òun dojú ìjà kọ wọ́n rí bí?

Ka pipe ipin Onídájọ́ 11