Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 11:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Jẹ́fítà ará Gílíádì jẹ́ akọni jagunjagun. Gílíádì ni baba rẹ̀; ṣùgbọ́n ìyá rẹ̀ jẹ́ aṣẹ́wó.

2. Ìyàwó Gílíádì sì bí àwọn ọmọkùnrin fún un, nígbà tí àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí dàgbà, wọ́n rán Jẹ́fità jáde kúrò nílé, wọ́n wí pé, “Ìwọ kì yóò ní ogún kankan ní ìdílé wa, nítorí pé ìwọ jẹ́ (ọmọ aṣẹ́wó) ọmọ obìnrin mìíràn.”

3. Jẹ́fità sì sá kúrò lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, ó sì pàgọ́ sí ilẹ̀ Tóbù, ó sì ń gbé níbẹ̀, níbẹ̀ ni àwọn ènìyàn kan ti ń tẹ ofìn lójú para pọ̀ láti máa tẹ̀lé e kiri.

4. Ní àsìkò kan, nígbà tí àwọn ará Ámónì dìde ogun sí àwọn Ísírẹ́lì,

5. Àwọn ìjòyè: aṣíwájú Gílíádì tọ Jẹ́fítà lọ láti pè é wá láti ilẹ̀ Tóbù.

6. Wọ́n wí fún Jẹ́fità wí pé, “Wá kí o sì jẹ́ olórí ogun wa kí a lè kọjú ogun sí àwọn ará Ámónì.”

7. Jẹ́fítà sì dáhùn pé, “Ṣé kì í ṣe pé ẹ kóríra mi tí ẹ sì lé mi kúrò ní ilé baba mi? Kí ló dé tí ẹ fi tọ̀ mí wá báyìí nígbà tí ẹ wà nínú wàhálà?”

8. Àwọn ìjòyè: àgbà Gílíádì dáhùn pé, “Nítorí rẹ̀ ni àwa fi yípadà sí ọ báyìí: tẹ̀lé wa, kí a lè dojú ìjà kọ àwọn ará Ámónì, ìwọ yóò sì jẹ olórí wa àti gbogbo àwa tí ń gbé ní Gílíádì.”

9. Jẹ́fità dáhùn pé, “Bí ẹ̀yin bá mú mi padà láti bá àwọn ará Ámónì jà àti tí Olúwa bá fi wọ́n lé mi lọ́wọ́: ṣe èmi yóò jẹ́ olórí yín nítòótọ́.”

10. Àwọn ìjòyè Gílíádì dáhùn pé, “Àwa fi Olúwa ṣe ẹlẹ́rìí: àwa yóò ṣe ohunkóhun tí o bá wí.”

Ka pipe ipin Onídájọ́ 11