Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 7:80-89 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

80. Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì méwàá tí ó kún fún tùràrí;

81. Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan àgbò kan, àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

82. Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

83. Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún, wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Áhírà ọmọ Énánì.

84. Wọ̀nyí ni ọrẹ tí àwọn olórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú wá fún ìyàsímímọ́ pẹpẹ nígbà tí wọ́n ta òróró sí i lórí: àwo fàdákà méjìlá, àwokòtò méjìlá, àwo wúrà méjìlá.

85. Àwo fàdákà kọ̀ọ̀kan wọn àádóje (130) ṣékélì, àwokòtò kọ̀ọ̀kan sì wọn àádọ́rin (70). Àpapọ̀ gbogbo àwo fàdákà jẹ́ egbèjìlá ṣékélì (2,400) gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́.

86. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwó wúrà méjìlá tí tùràrí kún inú wọn ṣékélì mẹ́wàá mẹ́wàá gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́. Àpapọ̀ ìwọ̀n gbogbo àwo wúrà jẹ́ ọgọ́fà ṣékélì (120)

87. Àpapọ̀ iye ẹran fún ẹbọ sísun jẹ́ akọ ọ̀dọ́ màlúù méjìlá, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan méjìlá pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ. Akọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ méjìlá.

88. Àpapọ̀ iye ẹran fún ọrẹ àlàáfíà jẹ́ màlúù mẹ́rìnlélógún (24), ọgọ́ta (60) àgbò, ọgọ́ta (60) akọ ewúrẹ́ àti ọgọ́ta (60) akọ ọ̀dọ́ màlúù ọlọ́dún kan. Wọ̀nyí ni ọrẹ ìyàsímímọ́ pẹpẹ lẹ́yìn tí a ta òróró sí i.

89. Nígbà tí Mósè wọ inú Àgọ́ Ìpàdé láti bá Olúwa sọ̀rọ̀, Olúwa sì sọ̀rọ̀ sí i láti àárin àwọn kérúbù méjì láti orí ìtẹ́ àánú tó bo àpótí ẹ̀rí, ohùn náà sì bá Mósè sọ̀rọ̀.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 7