Nígbà tí Mósè wọ inú Àgọ́ Ìpàdé láti bá Olúwa sọ̀rọ̀, Olúwa sì sọ̀rọ̀ sí i láti àárin àwọn kérúbù méjì láti orí ìtẹ́ àánú tó bo àpótí ẹ̀rí, ohùn náà sì bá Mósè sọ̀rọ̀.