Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 5:10-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ọrẹ ohun mímọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan jẹ́ ti oun nikan Ṣùgbọ́n ohunkóhun tó bá fún àlùfáà yóò jẹ́ ti àlùfáà.’ ”

11. Olúwa sọ fún Mósè wí pé,

12. “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ kí o sọ fún wọn pé: ‘Bí ìyàwó ọkùnrin kan bá yapa tó sì ṣe àìsòótọ́ sí i,

13. Nípa mímú kí ọkùnrin mìíràn bá a lò pọ̀ tí ó sì fi èyí pamọ́ fún ọkọ rẹ̀, tí a kò si gbá a mú nínú ìwà àìmọ́ rẹ̀ (nítorí pé kò sí ẹlẹ́rìí àti pé wọn kò ká a mọ́ nígbà tí ó ń dẹ́ṣẹ̀ náà).

14. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀mí owú jíjẹ bá bà lé ọkọ rẹ̀ débi pé ó ń furà sí ìyàwó rẹ̀ yìí tí ìyàwó rẹ̀ sì wà ní àìmọ́ nítòótọ́, tàbí tí ẹ̀mí owú bá bà lé ọkùnrin kan tó sì ń jowú ìyàwó rẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wà ní mímọ́,

15. nígbà náà ni ọkùnrin yìí yóò mú ìyàwó rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ àlùfáà. Ọkùnrin náà yóò sì mú ọrẹ tí a yàn fún obìnrin náà, ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n éfà ìyẹ̀fun bálì. Kò gbọdọ̀ da òróró sí i, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ fi tùràrí dídùn sí i nítorí pé ẹbọ ohun jíjẹ fún owú ni, èyí ti n mú ẹ̀ṣẹ̀ wá sí ìrántí.

16. “ ‘Àlùfáà yóò sì mú-un wá ṣíwájú Olúwa.

17. Àlùfáà yóò sì bu erùpẹ̀ ilẹ̀ àgọ́ sínú omi mímọ́ tó bù láti ìkòkò amọ̀,

18. Lẹ́yìn èyí, àlùfáà yóò mú obìnrin náà dúró níwájú Olúwa yóò sì tú irun orí obìnrin náà lée lọ́wọ́, èyí ni ẹbọ ohun jíjẹ ti owú, àlùfáà fúnra rẹ̀ yóò sì gbé omi kíkorò tí ń mú ègún lọ́wọ́.

19. Àlùfáà yóò sì mú obìnrin náà búra, yóò wí pé, “Bí ọkùnrin mìíràn kò bá bá ọ lòpọ̀, tí ó kò sì yapa, tí o kò sì di aláìmọ́ níwọ̀n ìgbà tí ó wà lábẹ́ àṣẹ ọkọ rẹ̀, a jẹ́ pé omi kíkorò tí ń mú ègún wá yìí kò ní se ọ́ níbi.

20. Ṣùgbọ́n tí ìwọ bá ti yapa kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ, tí o bá ti ba ara rẹ jẹ́ nípa jíjẹ́ kí ọkùnrin tí kì í se ọkọ rẹ bá ọ lò pọ̀,”

21. nígbà náà ni àlùfáà yóò mú obìnrin náà búra, yóò sọ fún obìnrin náà pé: “Kí Olúwa sọ ọ́ di ẹni ègún àti ẹni ìbáwí láàrin àwọn ènìyàn rẹ nípa mímú kí itan rẹ jẹrà, kí ikùn rẹ sì wú.

22. Ǹjẹ́ kí omi yìí tí ń mú ègún wá wọ inú ara rẹ, kí ó mú ikùn rẹ̀ wú, kí ó sì mú itan rẹ̀ jẹra dànù.”“ ‘Obìnrin náà yóò sì wí pé, “Àmín. Bẹ́ẹ̀ ni kó rí.”

23. “ ‘Nígbà náà ni àlùfáà yóò kọ ègún yìí sínú ìwé, yóò sì sìn ín sínú omi kíkoro náà.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 5