Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 35:21-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Tàbí pẹ̀lú ìjà gbangba lù ú pẹ̀lú ìkúùkù tí ó sì kú, pípa ni a ó pa ẹni bẹ́ẹ̀; apànìyàn ni. Olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ yóò pa apànìyàn náà tí ó bá bá a.

22. “ ‘Ṣùgbọ́n bí ó bá fi nǹkan gún un lójijì láìṣọ̀ta, tàbí tí ó sọ ohunkóhun lù ú láìmọ̀-ọ́n-mọ̀ ṣe

23. tàbí, láìri, ju òkúta sí tí ó lè pa á, tí ó sì kú, nígbà tí kì í ṣe ọ̀ta rẹ̀, láti ṣe é léṣe,

24. Àwọn àpèjọ gbúdọ̀ dájọ́ láàrin rẹ̀ àti olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà.

25. Àpèjọ gbọ́dọ̀ dá ààbò bo ẹni tí a fi ẹ̀sùn ìpànìyàn kàn, kí a sì ran-an padà lọ sí ìlú ìsásí tí ó ti wá. Ó gbúdọ̀ dúró níbẹ̀ títí di ìgbà tí olórí àlùfáà bá kú, ẹni tí a fi àmì òróró yàn.

26. “ ‘Ṣùgbọ́n ti ẹni tí a fi sùn kan bá jáde kọjá ààlà ìlú ìsásí tí ó sá sí.

27. Tí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ sì ri ní ìta ìlú náà, olùgbẹ̀san lè pa ẹni tí a fi ẹ̀sùn kàn láì jẹ́bi ẹ̀sùn ìpànìyàn.

28. Ẹni tí a fi ẹ̀sùn kàn gbọdọ̀ dúró nínú ìlú ìsásí títí di ìgbà tí olórí àlùfáà bá kú; lẹ́yìn ikú olórí àlùfáà, ni ó tó lè padà sí ibi tí dúkìá rẹ̀ wà.

29. “ ‘Wọ̀nyí ni ó jẹ́ ìlànà ìdájọ́ fún yín ní ìran yín tó ń bọ̀, ní ibikíbi tí ẹ bá ń gbé.

30. “ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ènìyàn gbọdọ̀ kú gẹ́gẹ́ bí apànìyàn lórí ìjẹ́rìí àwọn ènìyàn. Ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí kanṣoṣo. Kì yóò jẹ́ri sí ẹnìkan láti pa.

31. “ ‘Má ṣe gba ohun ìràpadà fún ẹ̀mí olùpànìyàn, tí ó yẹ kí ó kú. A gbọ́dọ̀ pa á.

32. “ ‘Má ṣe gba ìràsílẹ̀ fún ẹnikẹ́ni tí ó bá lọ sí ìlú ìsásí, pe kí ó padà máa gbé ní ilẹ̀ tirẹ̀ kí ó tó di ìgbà ikú olórí àlùfáà.

33. “ ‘Má ṣe sọ ilẹ̀ tí ẹ wà di àìmọ́. Ìtàjẹ̀ sílẹ̀ sọ ilẹ̀ náà di àìmọ́. Atúnṣe kì yóò sí fún ilẹ̀ tí a ti ta ẹ̀jẹ̀ lé lórí, àyà fi ẹ̀jẹ̀ ẹni tí ó ta á sílẹ̀.

34. Má se sọ di àìmọ́, ilẹ̀ tí ẹ ń gbé, àti èyí tí mo ń gbé, nítorí Èmi JÈHÓFÀ, ń gbé láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.’ ”

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 35