Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 34:7-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. “ ‘Fún ààlà ìhà-àríwá, fa ìlà láti òkun ńlá lọ sí orí òkè Hórì

8. Àti láti orí-òkè Hórì sí Lébò Hámátì. Nígbà náà ààlà náà yóò lọ sí Sédádì,

9. Tẹ̀ṣíwájú lọ sí Sífírónì, kí o sì fò pín si ní Hasari-Énánì, Èyí yóò jẹ́ ààlà tìrẹ ní ìhà àríwá.

10. “ ‘Kí ẹ sì sàmì sí ilẹ̀ ti yín ní ìhà ìlà oòrùn láti Hasari-Énánì lọ dé Ṣéfámù.

11. Ààlà náà yóò ti Séfámù sọ̀kalẹ̀ wá lọ sí Ríbílà ní ìhà-ìlà oòrùn Háínì, kí o sì sọ̀kalẹ̀ lọ dé ìhà Òkun Kínérétì ní ìhà ìlà oòrùn.

12. Nígbà náà, ààlà náà yóò sọ̀kalẹ̀ lọ sí apá Jọ́dánì, yóò sì dópin nínú Òkun.“ ‘Èyí yóò jẹ́ ilẹ̀ yín, pẹ̀lú ààlà tirẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà.’ ”

13. Mósè pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Yan ilẹ̀ yìí pẹ̀lú kèké gẹ́gẹ́ bí ìní ogún: Olúwa ti paláṣẹ láti fi fún ẹ̀yà mẹ́san, àti ààbọ̀.

14. Nítorí ará ilẹ ẹ̀yà ti Rúbẹ́nì, ẹ̀yà ti Gádì àti ẹ̀yà ààbọ̀ ti Mánásè ti gba ogún ti wọn.

15. Ẹ̀yà méjèèjì àti ààbọ̀ yìí ti gba ogún ti wọn ní ìhà Jódánì létí i Jéríkò, Gábásì, ní ìhà ìlà oòrùn.”

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 34