Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 34:11-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ààlà náà yóò ti Séfámù sọ̀kalẹ̀ wá lọ sí Ríbílà ní ìhà-ìlà oòrùn Háínì, kí o sì sọ̀kalẹ̀ lọ dé ìhà Òkun Kínérétì ní ìhà ìlà oòrùn.

12. Nígbà náà, ààlà náà yóò sọ̀kalẹ̀ lọ sí apá Jọ́dánì, yóò sì dópin nínú Òkun.“ ‘Èyí yóò jẹ́ ilẹ̀ yín, pẹ̀lú ààlà tirẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà.’ ”

13. Mósè pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Yan ilẹ̀ yìí pẹ̀lú kèké gẹ́gẹ́ bí ìní ogún: Olúwa ti paláṣẹ láti fi fún ẹ̀yà mẹ́san, àti ààbọ̀.

14. Nítorí ará ilẹ ẹ̀yà ti Rúbẹ́nì, ẹ̀yà ti Gádì àti ẹ̀yà ààbọ̀ ti Mánásè ti gba ogún ti wọn.

15. Ẹ̀yà méjèèjì àti ààbọ̀ yìí ti gba ogún ti wọn ní ìhà Jódánì létí i Jéríkò, Gábásì, ní ìhà ìlà oòrùn.”

16. Olúwa sọ fún Mósè pé,

17. “Èyí ni orúkọ àwọn ọkùnrin náà tí yóò pín ilẹ̀, náà fún yín gẹ́gẹ́ bí ogún: Élíásárì àlùfáà àti Jóṣúà ọmọ Núnì.

18. Kí o sì yan olórí kan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan láti pín ilẹ̀ náà.

19. Èyí ni orúkọ wọn:Kálẹ́bù ọmọ Jéfúnè,láti ẹ̀yà Júdà;

20. Ṣémúélì ọmọ Ámíhúdì,láti ẹ̀yà Ṣíméónì;

21. Élídádì ọmọ Kísílónì,láti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì;

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 34