Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 34:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa sọ fún Mósè pé,

2. “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí o sì sọ fún wọn pé: ‘Tí ẹ bá wọ Kénánì, ilẹ̀ tí a ó fi fún yín, gẹ́gẹ́ bí ogún yín yóò ní ààlà wọn yí:

3. “ ‘Ìhà gúṣù yín yóò bọ́ sí ara ihà Ṣínì lẹ́bá Édómù, àti ìlà-oòrùn, ààlà ìhà-gúsù yóò bẹ̀rẹ̀ láti òpin Òkun Iyọ̀,

4. Kọjá lọ sí Síkọ́píọ́nì, tẹ̀ṣíwájú lọ si Sínì: kó bọ́ si gúsù Kadesi-Báníyà, kí o sì dé Hasari-Ádárò, kí o sì kọjá sí Ásímónì.

5. Níbẹ̀ ni yóò ti padà, papọ̀ mọ́ odò Éjíbítì, tí yóò sì parí ní òpin Òkun.

6. “ ‘Ìhà ìwọ̀ oòrùn yín yóò jẹ́ òpin lórí Òkun ńlá. Èyí yóò jẹ́ ààlà yín lórí ìhà-ìwọ̀ oòrùn:

7. “ ‘Fún ààlà ìhà-àríwá, fa ìlà láti òkun ńlá lọ sí orí òkè Hórì

8. Àti láti orí-òkè Hórì sí Lébò Hámátì. Nígbà náà ààlà náà yóò lọ sí Sédádì,

9. Tẹ̀ṣíwájú lọ sí Sífírónì, kí o sì fò pín si ní Hasari-Énánì, Èyí yóò jẹ́ ààlà tìrẹ ní ìhà àríwá.

10. “ ‘Kí ẹ sì sàmì sí ilẹ̀ ti yín ní ìhà ìlà oòrùn láti Hasari-Énánì lọ dé Ṣéfámù.

11. Ààlà náà yóò ti Séfámù sọ̀kalẹ̀ wá lọ sí Ríbílà ní ìhà-ìlà oòrùn Háínì, kí o sì sọ̀kalẹ̀ lọ dé ìhà Òkun Kínérétì ní ìhà ìlà oòrùn.

12. Nígbà náà, ààlà náà yóò sọ̀kalẹ̀ lọ sí apá Jọ́dánì, yóò sì dópin nínú Òkun.“ ‘Èyí yóò jẹ́ ilẹ̀ yín, pẹ̀lú ààlà tirẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà.’ ”

13. Mósè pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Yan ilẹ̀ yìí pẹ̀lú kèké gẹ́gẹ́ bí ìní ogún: Olúwa ti paláṣẹ láti fi fún ẹ̀yà mẹ́san, àti ààbọ̀.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 34