Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 31:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa sọ fún Mósè pé,

2. “Gbẹ̀san lára àwọn Mídíánì fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Lẹ́yìn ìgbà náà a ó kó ọ jọ pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ.”

3. Mósè sì sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ wọ ìhámọ́ra ogun fún àwọn kan nínú yín láti lọ da ojú ìjà kọ àwọn ọmọ Mídíánì láti gba ẹ̀san Olúwa lára wọn.

4. Rán ẹgberún (1000) ọmọ ogun láti ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ní Ísírẹ́lì.”

5. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì yan nínú àwọn ẹgbẹgbẹ̀rún ènìyàn Ísírẹ́lì, ẹgbẹ̀rún (1000) ènìyan láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, ẹgbàá mẹ́fà (12,000) ènìyàn tí ó wọ ìhámọ́ra ogun.

6. Mósè rán wọn lọ sí ogun, ẹgbẹ̀rún (1000) láti ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú Fínéhásì ọmọ Élíásárì, ti ó jẹ́ àlùfáà, ti òun ti ohun èlò ibi mímọ́ àti ìpè wọ̀n-ọn-nì ní ọwọ́ rẹ̀.

7. Wọ́n dojú ìjà kọ Mídíánì gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti láṣẹ fún Mósè, kí wọn sì pa gbogbo wọn.

8. Wọ́n sì pa àwọn ọba Mídíánì pẹ̀lú: àwọn ìyókù tí wọ́n pa lára wọn ni Éfì, Rékémù, Ṣúrù àti Húrì, àti Rébà: ọba Mídíánì márùn ún, wọ́n sì fi idà pa Bálámù ọmọ Béórì.

9. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì mú gbogbo obìnrin Mídíánì ní ìgbékùn àti àwọn ọmọ kékeré wọn, wọ́n sì kó gbogbo ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo agbo ẹran wọn àti gbogbo ẹrù wọn.

10. Wọ́n finá jó gbogbo ìlú wọn àti ibùdó wọn.

11. Wọ́n sì kó gbogbo ìní wọn, àti ènìyàn àti ẹran.

12. Wọ́n sì kó gbogbo ohun tí wọ́n bàjẹ́ àti ènìyàn àti ẹran wá sọ́dọ̀ Mósè àti Élíásárì àlùfáà, àti sọ́dọ̀ ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ibùdó àgọ́ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù tí ń bẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jọ́dánì létí Jẹ́ríkò.

13. Mósè, Élíásárì àlùfáà àti gbogbo olórí ìgbéríko lọ láti lọ bá wọn ní ìta ibùdó.

14. Inú bí Mósè sí àwọn olórí ọmọ ogun, pẹ̀lú àwọn olórí ẹgbẹ̀rún (1000) àti olórí ọrọrún (1000) tí wọ́n ti ogun dé.

15. Mósè sì bèèrè wí pé, “Ẹ̀yin ha dá gbogbo àwọn obìnrin sí bí?

16. Àwọn ni wọ́n tẹ̀lé ìmọ̀ràn Bálámù, àwọn ní ó ṣe okùnfà yíyí àwọn ọ̀mọ̀ Ísírẹ́lì padà kúrò ní ọ̀dọ̀ Olúwa nínú èyí tí ó ṣẹlẹ̀ ní Péórì, nibi tí àjàkálẹ̀-àrùn ti kọlu àwọn ènìyàn Olúwa.

17. Nísinsìnyìí, pa gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin àti àwọn obìnrin tí ó ti súnmọ́ ọkùnrin,

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 31